Ọlawale Ajao, Ibadan
Wahala mi-in tun n rúgbó bọ̀ niluu Ayétẹ̀, nijọba ibilẹ Ariwa Ìbàràpá bayii, pẹlu bi Fúlàní kan ti wọn n pe ni Iskilu Wakil ṣe n dúkookò iku mọ awọn ọmọ bibi ilu naa.
ALAROYE gbọ pe lati Ọjọbọ, Tọ́sìdeè, to kọja, ni Wakil, ọkan ninu awọn Fúlàní to n gbe ilu Ayétẹ̀, ti di ẹrujẹjẹ sí awọn araalu naa lọrun pẹlu bo ṣe lọọ di oju ọna to já sì inu abule to n gbe, ko si jẹ kí awọn eeyan ti wọn n gba ibẹ lọ sinu ọkọ tiwọn ribi ba kọja.
Wahala ọhun bẹrẹ nigba ti awọn ònilẹ̀ sọ fún ọkunrin Fúlàní yii lati fi ori ilẹ nla ti oun atawọn ẹmẹwa rẹ n gbe, ti wọn si fi n dáko silẹ, nitori niṣe ni wọn n fi awọn maaluu wọn bá nnkan oko awọn agbẹ agbegbe naa jẹ, bẹẹ, ki i ṣe pe o ralẹ̀ naa lọwọ àwọn.
Ọrọ yìí ni wọn lo bí Wakil ninu to fi tutọ́ sókè, to fojú gba a, o ni ko si baba nla ẹni to le lé oun kuro lori ilẹ ọhun.
Olugbe ilu Ayétẹ̀ to fìdí iṣẹlẹ yii mulẹ f’ALAROYE ṣalaye pe “Gbogbo ibi ti awọn Wakil n gbe ni wọn ti sọ di abule. Gbogbo ọna to já sí abule yii ni wọn ti kó igi nla nla di.
“Wakil ní gbogbo ẹni tó bá gba ọna yii kọja loun máa pa, nitori jagunjagun loun, oun kúrò ni ẹni tí ẹnìkan le ba dan pálapàla wò rara ni toun.
“Lati ọjọ Ẹti, Furaidee, lawọn Amọtẹkun ti dé si Ayẹtẹ, nitori awọn alaṣẹ ilu to fi ọrọ yii to ijọba leti. Ṣugbọn lati ọjọ yẹn ti awọn Amọtẹkun ti de, wọn kò rí nnkan kan ṣe, wọn kan n fẹsẹ̀ gbálẹ̀ kiri aarin ilu ni, nitori ijọba ko fún wọn ní irin iṣẹ ti wọn le lò.
“Nigba tawọn araalu fẹẹ sọ ọrọ yii di nnkan mi-in mọ awọn Amọtẹkun lọwọ ni wọn sọ pe ọga awọn ti lọ sí olú ileeṣẹ n’Ibadan lati lọọ gba irin-iṣẹ́ tí àwọn máa lò wa.
“Awọn agbẹ ko le lọ sinu oko wọn mọ bayii, kaluku kan n fẹsẹ̀ palẹ̀ kiri ni.
“Awọn ọdẹ ilu ṣetán láti lọọ kojú wọn, ṣugbọn ẹru ijọba apapọ lo n ba wọn, wọn mọ pé awọn ko le ba Fúlàní ja ki ijọba apapọ ma fiya jẹ awọn.
“Ìyẹn naa lo jẹ kí awọn Fúlàní máa gbé Wakil ga kọjá agbára rẹ. Wọn ni bo ba wù wá, ka lọọ pe Sunday Ìgbòho, niṣe ni Wakil máa pa a toun tàwọn ọmọ ogun ẹ.”