Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Pẹlu bi ibo gomina ipinlẹ Ekiti ṣe ku ọdun kan ati oṣu diẹ, Gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Oloye Ṣẹgun Oni, ti ṣi ọfiisi ipolongo siluu Ado-Ekiti, o si ti ṣeleri pe dandan ni ki ẹgbẹ oṣelu All Progessives Congress (APC) lọ.
Lọjọ Aje, ,Mọnde, oni, ni Oni ṣi ọfiisi naa to pe ni ‘Ile Mọlẹbi PDP’ sagbegbe Adebayọ, nibi tawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP) ti kora jọ.
Nigba to n kede erongba ẹ lati dupo gomina lọdun 2022, Oni ṣalaye pe oun yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu araalu, Ayọdele Fayoṣe toun naa jẹ gomina Ekiti tẹlẹ ati Sẹnetọ Biọdun Olujimi lati gbajọba lọwọ APC.
Oni ni ti nnkan ko ba yipada, oun yoo dupo gomina ti Ọlọrun ba fẹ, ati pe APC to wa lori aleefa bayii ko lagbara to bi wọn ṣe rọ.
‘‘PDP Ekiti ko bẹru ẹgbẹ to n ṣejọba lọwọ tabi agbara ijọba apapọ ti wọn ni. Lasiko kan ninu itan ilẹ yii, PDP lo n ṣejọba, ṣugbọn awọn ọmọ Naijiria yi ọkan wọn pada, wọn si dibo fun APC ni 2015.
‘‘Tẹ ẹ ba wo nnkan tawọn eeyan n sọ nigboro lasiko yii, wọn ti yi ọkan wọn pada. Awọn araalu ko fẹ APC mọ lẹyin iṣejọba Fayẹmi.’’
Agba oloṣelu naa ni ko sẹni ti ko le fidi-rẹmi lasiko ibo nitori bi Donald Trump ṣe lagbara to, o ja walẹ ni. O ni oun fi eyi fa awọn oloṣelu leti, ki ẹnikẹni ma ṣe gbero magomago ibo kankan mọ nitori iru igbesẹ bẹẹ ki i pẹ.
O waa ni ifọwọsowọpọ ati ifẹ loun mu wa bayii, ki onikaluku fi ootọ inu ṣe oṣelu to wa lode bayii ko le jẹ ọna abayọ si awọn iṣoro to wa nilẹ.