Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Titan ti de ba gende-kunrin kan, Owolabi Oludipẹ, ti wọn n pe ni Sọmọri, ẹni ti wọn ni ogbologboo ọmọ ẹgbẹ okunkun ni i ṣe nipinlẹ Ogun.
Niṣe loun atawọn ẹgbẹ ẹ kọju ija sawọn ọlọpaa lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kin-in-ni, l’Odogbolu, nibẹ ni wọn ti n yinbọn mọ Sọmọri, lo ba dagbere faye.
Awọn ọlọpaa ti n wa Sọmọri tẹlẹ, gẹgẹ bi Alukoro wọn nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe wi.
Afi bi wọn ṣe ri i lagbegbe Ita-Ado, l’Odogbolu, lọjọ Sannde naa, lasiko toun atawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aye to n ṣe n gbiyanju lati fajangbọn laduugbo naa. Awọn kan ni wọn ta awọn ọlọpaa lolobo pe ọkunrin yii atawọn ẹgbẹ ẹ tun ti fẹẹ bẹrẹ wahala wọn, n ni DPO Odogbolu fi ko awọn ọmọọṣẹ rẹ lọ sibẹ.
Bi wọn ṣe ri awọn ọlọpaa ni wọn bẹrẹ si i yinbọn si awọn agbofinro naa, bo ṣe di pe awọn iyẹn naa rọjo ibọn fun wọn pada niyẹn. Nibi ija naa ni ibọn ti ba olori ogun awọn ẹgbẹ okunkun, Sọmọri.
Awọn ọlọpaa gbe e lọ sọsibitu, ṣugbọn o ku nibi to ti n gba itọju lọwọ. Awọn mi-in naa fara gbọta ninu awọn ọmọ ogun ẹ, wọn gbe ọta ibọn sa lọ.
Sọmọri yii ni wọn lo pa Runṣewe Ṣẹgun, oṣiṣẹ ajọ Sifu Difẹnsi, lọjọ kẹrinla, oṣu keji, ọdun 2020, ati Sunday Kayọde Adegbuyi, ẹni to pa lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji, ọdun 2020. Bakan naa ni wọn lo tun pa Shoyọmbọ Sanyaolu Fakọya, ẹni to jẹ olori ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ, lọjọ kọkanla, oṣu kọkanla, ọdun 2020, kan naa, nibi ti wọn ti n ja ija agba.
Awọn ọlọpaa sọ pe gbogbo ipaniyan yii ni Sọmọri jẹwọ ẹ pe oun ṣe nigba to n gba itọju lọwọ lọsibitu, wọn lo jẹwọ ẹṣẹ rẹ ko too ku.
Ni bayii, ọga ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Edward Ajogun, ti paṣẹ pe ki wọn wa awọn yooku ninu ẹgbẹ okunkun naa ri, iyẹn awọn to sa lọ. Bẹẹ lo gboriyin fawọn ọlọpaa to mu Sọmọri balẹ, o ki wọn ku iṣẹ takuntakun.