Ibọn awọn kọsitọọmu ba Lekan laya l’Orile-Imọ, lo ba ku patapata

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Ọkunrin kan ti wọn pe ni Lekan padanu ẹmi ẹ laaarọ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ keji, oṣu keji, ọdun 2021 yii, nigba ti awọn kọsitọọmu yinbọn lu u pẹlu awọn mẹta mi-in ti wọn jọ jẹ onifayawọ, lagbegbe Orile-Imọ, Ita Osu, loju ọna marosẹ Ṣagamu si Abẹokuta.

Bo tilẹ jẹ pe awọn mẹta yooku ti ibọn ba ko ku, sibẹ, ileewosan ni wọn wa lasiko ti a n kọ iroyin yii lọwọ.

Ohun to ṣẹlẹ gẹgẹ bawọn onifayawọ naa ṣe ṣalaye nigba ti wọn fẹhonu han lọ si ọfiisi gomina l’Oke-Mosan, ni pe awọn kọsitọọmu mọ-ọn-mọ waa da awọn lọna ni.

Wọn ni kawọn too ko awọn ọja ofin yii ja oju ọna rara lawọn ti pe awọn aṣọbode to maa n wa loju ọna Ita Osu, pe awọn fẹẹ kọja pẹlu iye ọja bayii, awọn si ti fun wọn lowo to yẹ kawọn fun wọn ko too di pe awọn yoo kọja rara.

Awọn onifayawọ naa sọ pe ko si igba tawọn fun wọn lowo ti ko ni i jẹ pe wọn yoo tun lọọ dena de awọn lọna, ti wọn yoo fẹẹ gba ọja awọn. Wọn ni ohun to ṣẹlẹ laaarọ ọjọ yii ree, awọn ti fun wọn ni miliọnu kan naira kawọn kọsitọọmu naa too tun ran awọn ikọ mi-in ninu wọn wa lati da awọn lọna, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn.

Koda, wọn ni wọn tun pe awọn eeyan wọn lati Ikẹja, pe ki wọn waa kun awọn lọwọ, afigba ti wọn yinbọn pa ọkan lara awọn loju wọn too walẹ.

Awọn onifayawọ yii sọ pe awọn ko niṣẹ mi-in tawọn le ṣe, bẹẹ lawọn ko le jale, awọn ko si lọ si Kutọnu lọọ ko mọto ati irẹsi wa, ipinlẹ Ogun naa lawọn ti n ra a, nigba tawọn ba fẹẹ gbe e e kọja laarin ipinlẹ Ogun naa ni wọn yoo tun maa le awọn kiri.

Nigba to n pẹtu si wọn lọkan, Akọwe ijọba ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Tokunbọ Talabi, sọ pe kawọn onifayawọ naa ṣe suuru, nitori ijọba yoo gbe ohun ti wọn n sọ yii yẹwo.

O fi kun un pe ijọba yoo ṣabẹwo sile awọn ẹbi Lekan to doloogbe, wọn yoo si sanwo itọju awọn to wa lọsibitu, ṣugbọn o rọ wọn lati lọọ wa iṣẹ mi-in ṣe, nitori ofin ko faaye gba fayawọ, iṣẹ to lodi sofin gbaa ni.

A

Leave a Reply