Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Kọmiṣanna feto idajọ nipinlẹ Ekiti, Amofin Wale Fapohunda, ti gbe ọga-agba ọlọpaa nilẹ yii, kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa ati ajọ to n ṣakoso iṣẹ ọlọpaa lọ sile-ẹjọ lori ọrọ Omidan Ọlajide Ọmọlọla ti wọn yọ niṣẹ nitori oyun.
Ṣe lọsẹ to lọ lọhun-un nileeṣẹ ọlọpaa le ọmọbinrin to jẹ konstebu ni teṣan Iye-Ekiti, nijọba ibilẹ Ilejemeje, ọhun lẹnu iṣẹ nitori o loyun lasiko ti ofin iṣẹ naa ko ti i fun un lanfaani lati ṣe bẹẹ.
A gbọ pe oṣu karun-un, ọdun to kọja, ni ọmọbinrin yii jade nileewe awọn ọlọpaa, bẹẹ lo ti loyun oṣu mẹfa lasiko ti wọn le e, ofin iṣẹ naa si ni pe lẹyin ọdun meji lo too le lọkọ, lẹyin ọdun mẹta lo si too le loyun.
Lẹyin igbesẹ naa ni CP Tunde Mobayọ to jẹ Kọmiṣanna ọlọpaa Ekiti sọ fun ALAROYE pe tobinrin ba wa nileewe ọlọpaa, ko le loyun, to ba si tun jade tan, o gbọdọ duro ko too lọkọ tabi loyun nitori awọn idanilẹkọọ ati igbaradi mi-in ti too ṣe.
Abala kẹtadinlaaadoje (127) alakalẹ ileeṣẹ ọlọpaa lo ni wọn fi ṣedajọ ọmọbinrin naa, eyi to ni obinrin ti ko ba ti i lọkọ to ba loyun, ileeṣẹ ọlọpaa yoo le e, ọga-agba ọlọpaa patapata nikan lo si le yi igbesẹ naa pada.
Eyi lo jẹ kijọba Ekiti pe ẹjọ kan sile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa niluu Ado-Ekiti, lẹyin ti wọn ni awọn gba iwe ẹhonu latọdọ ẹgbẹ awọn obinrin amofin atawọn mi-in to n ja fun ẹtọ awọn obinrin.
Ninu iwe ipẹjọ naa to ni nọmba ( FHC/ AD/ CS/ 8/ 2021) ni wọn ti ni ki kootu naa ṣagbayewọ abala kẹtadinlaaadoje (127) tileeṣẹ naa lo ni ibamu pẹlu abala kẹtadinlogoji (37) ati ikejilelogoji (42) ofin ilẹ Naijiria boya ko ta ko ara wọn, bẹẹ ni ki wọn tun wo awọn ofin ẹtọ ọmọniyan kaakiri agbaye, eyi ti Naijiria n tẹle.
Fapohunda ni ijọba duro lori ipinnu rẹ lati pa gbogbo igbesẹ to n tẹ ẹtọ awọn obinrin mọlẹ, eyi si lo fa oriṣiiriṣii ofin ati alakalẹ, igbesẹ awọn ọlọpaa si ta ko awọn ofin ọhun.
Bakan naa ni kọmiṣanna ọhun ni oun ti kọ lẹta si ọga-agba ọlọpaa l’Abuja, iyẹn Mohammed Adamu, lori atilẹyin ijọba lati ba ileeṣẹ naa ṣagbeyẹwo awọn ofin ọjọ pipẹ ti wọn n lo.