Ọlawale Ajao, Ibadan
Ija igboro iba ṣẹlẹ laarin awọn Fúlàní darandaran atawọn ọdọ Yoruba n’Ibadan, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, Ọlọrun lo si mọ iye èèyàn ati dukia tí ìbá lọ sí í bi ko ṣe iṣẹ takuntakun tawọn agbofinro ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe lati kòòré wahala naa.
Yánpọyánrin ọhun ni iba ṣẹlẹ ni nnkan bíi aago marun-un irọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keje, oṣu kejì, ọdun yii, nígbà tí àwọn arinrinajo Fúlàní bíi ọgọ́rin (80) wọ igboro Ibadan lẹẹkan ṣoṣo.
Ninu ọkọ tirela ti wọn wa, eyi ti nọmba rẹ̀ jẹ KTG 220 ZZ (BAUCHI) la ti ri maaluu mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ati alupupu mẹtala.
Ipo àìbalẹ̀ ọkàn ti ilẹ Yorùbá wa lori iwa ipaniyan ati ijinigbe awọn Fúlàní ló mú kí àwọn ọmọ iṣọta to wa lagbegbe Iwo Road, n’Ibadan, maa mura lati kọ lu awọn àjèjì onimaaluu naa.
Ṣugbọn èèrà kò ti i rin awọn Fúlàní ti irinajo wọn kò àwọn ará Ìbàdàn láyà sókè yii ti awọn agbofinro ilẹ Yorùbá, Amọtẹkun, ẹka ipinlẹ Ọyọ, atawọn oṣiṣẹ Operation Burst ti i ṣe ikọ agbofinro ijọba ipinlẹ naa fi lọọ da awọn arinrinajo naa duro, ti wọn sì gbé wọn lọ sì agọ ọlọpaa to wa laduugbo Agodi, n’Ibadan.
Eyi lo si fopin sí ìkọlù ti iba waye láàrin ọdọ ti wọn ti n gbero lati kọ lu awọn Fúlàní naa.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti awọn ọlọpaa ṣe fawọn eeyan naa ni wọn ti sọ pé àwọn kò bá tìjà wa s’Ibadan, ipinlẹ Eko ati Ògùn gan-an lawọn n lọ gẹgẹ bí Agbẹnusọ fún ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CSP Olugbenga Fadeyi ṣe fìdí ẹ̀ múlẹ.
SCP Fadeyi fi kun ùn pe awọn to ni maaluu inu mọto naa sọ pe awọn nnkan ọsin ọhun naa lawọn n ko lọ sí odo ẹran to wa l’Agege, nipinlẹ Eko, láti tà, nigba ti awọn to ní àwọn alùpùpù naa sọ pe Too Geetì Ògèrè, nipinlẹ Ogun, lawọn ko awọn alùpùpù naa lọ fún iṣẹ ọkada.