Faith Adebọla, Eko
Tiroo lorukọ inagijẹ ẹ, ki i ṣe tiroo tawọn obinrin n le soju o, olori awọn bọisi laduugbo Agarawu, nisalẹ Eko lọhun-un, ni wọn pe Tiroo eleyii, ṣugbọn o ti doloogbe bayii, awọn ẹgbẹ bọisi adugbo si adugbo ti wọn n bara wọn ja ni wọn pa a.
Atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, DSP Olumuyiwa Adejọbi, fi ṣowọ s’ALAROYE ni lati alẹ ọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii, lawọn ọdọkunrin, awọn bọisi adugbo Agarawu ati Ọnala ti doju ija kọ ara wọn, Opopona Alli ni wọn patẹ ija si, ti wọn n le ara wọn kitakita kaakiri opopona kan si ekeji, wọn fẹẹ mọ ẹni to lagbara ju.
Adejọbi ni bi wọn ṣe n ja ija igba laarin ara wọn naa ni wọn n ṣe ara wọn leṣe, ti wọn si tun n kọ lu awọn araalu to n lọ jẹẹjẹ wọn. Awọn kan lara wọn lo anfaani naa lati ja ṣọọbu tawọn eeyan ti n taja lole, wọn n ko ẹru ẹlẹru, bẹẹ ni iro ibọn n dun lakọlakọ.
Wọn ni bawọn ọdọ yii ṣe n kọ lu awọn araalu lo bi Tiroo ninu, lo ba ko awọn ọmọlẹyin ẹ lọ si agbegbe Itafaji nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, pe tawọn alatako wọn ba fi le kọja, awọn maa ba wọn ja gidi ni.
Ṣugbọn lọwọ afẹmọju ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, nibọn ṣadeede ba Tiroo lẹyin ọrun, wọn ni niṣe lo pariwo, to si fidi janlẹ, lawọn ẹlẹgbẹ ẹ ba gbe e digbadigba lọ si ọsibitu aladaani kan to wa nitosi, ṣugbọn o ti dakẹ ki wọn too debẹ.
Alukoro ọlọpaa lawọn ti mu pupọ lara awọn janduku ọhun, o lawọn kan tọwọ ba ti jẹwọ pe olori ẹgbẹ okunkun ni Tiroo to ku yii, ati pe Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, ti fi ikọ ọlọpaa ayara-bii-aṣa RRS ati mọto atamatase meji ṣọwọ sagbegbe naa lati dẹrọ ija buruku ọhun.
O ni eruku ija naa ti n rọlẹ, awọn ọlọpaa si ti wa lojufo lati fi pampẹ ofin gbe ẹnikẹni to ba dalu ru, tori awọn ti gbọ pe awọn kan ṣi n leri pe awọn maa gbẹsan pipa ti wọn pa Tiroo.