Owo epo bẹntiroolu yoo tun lọ soke lẹẹkan si i o

 

Ijọba apapọ ti sọ pe iye tawọn araalu n ra epo bẹntiroolu yoo tun lọ soke lẹẹkan si i.

Ọgbẹni Timipre Sylva, ẹni ti ṣe minisita kekere fun ọrọ epo bẹntiroolu ti sọ pe ki awọn eeyan orilẹ-ede yii maa mura silẹ fun afikun iye ti wọn n ra epo bẹntiroolu, bi iye ti wọn n ra agba epo rọbi ṣe gbowo lori bayii lọja agbaye.

Minisita yii sọ pe epo rọbi ti di ọgọta dọla ($60) agba kan lagbaaye, ati pe ti ọrọ ba ti ri bayii, a jẹ pe iye ti awọn ọmọ Naijiria n ra jala epo bẹntiroolu yoo kuro ni iye ti wọn ra a, yoo tun wọn si i.

Ni bayii, iye ti wọn n ra jala kan wa laarin ọgọjọ naira (N160) si naira marun-un-din-laaadọsan-an (N165). Nigba ti epo rọbi wa ni dọla mẹtalelogoji ($43) ni nnkan bii oṣu mẹrin sẹyin ni wọn ṣe agbekalẹ ọhun.

Nibi ipade apero kan ti wọn ṣe niluu Abuja ni Sylva ti ta awọn ọmọ Naijriia lolobo pe iye ti wọn n ra jala epo bẹntiroolu yoo tun lọ soke lẹẹkan si i.

O ni idi ti owo ọhun yoo fi kuro ni iye tawọn eeyan n ra a bayii ni pe ijọba Buhari ko ni in lọkan, bẹẹ ni ko tun si ninu eto iṣuna ọdun 2021 yii, lati seto iranwọ lori iye ti wọn yoo maa ta epo. O ni bo tilẹ jẹ pe owo gọbọi ti wọn n ta epo rọbi yoo tun pawo wọle fun ijọba, sibẹ yoo ṣoro ki ijọba tun maa na ere ẹ yii sori eto iranwọ lori iye tawọn eeyan yoo maa ra jala epo bẹntiroolu.

Timipre Sylva sọ pe ohun idunnu ni pe orilẹ-ede yii yoo tun pawo repẹtẹ lori epo rọbi ẹ, ṣugbọn awọn eeyan orilẹ-ede yii naa gbọdọ gbaradi lati ra jala epo ju eyi ti wọn n ra a bayii.

Ṣa o, Aarẹ ọkan ninu ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ni Naijiria, Trade Union Congress, Quadri Ọlalẹyẹ, ti bu ẹnu atẹ lu ohun ti minisita yii sọ, bẹẹ lo sọ pe ko si ọrọ apọnle kankan ninu ohun to sọ kalẹ naa pe epo yoo tun wọn si i ni Naijiria.

O ni, tidunnu tidunnu ni ijọba Naijiria fi maa n sare kede awọn eto to le mu aye nira fawọn eeyan orilẹ-ede yii, ṣugbọn ti wọn ki i kọbi ara si ohun to le mu idẹrun ba wọn. Bakan naa lo fi kun un pe ijọba kan ti ko laaanu ni ijọba Buhari, ati pe o foju han daadaa pe awọn to n ṣejọba lasiko yii ko bikita bi nnkan ṣe nira fawọn ọmọ Naijiria bayii.

 

 

Leave a Reply