Florence Babaṣọla
Ọwọ awọn ikọ Sifu Difẹnsi ti tẹ ọkunrin kan, Adekunle Arẹmu, lori ẹsun pe o fẹẹ ba iyawo rẹ, Oyinade Ṣade, jokoo ṣedanwo igbaniwọle fawọn olukọ tijọba ipinlẹ Ọṣun n ṣe lọwọ.
Nibudo idanwo to wa ni CBT Center, ninu ọgba Ileṣa College of Education, Ileṣa, ni aṣiri Arẹmu ti tu l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Bi wọn ṣe fẹẹ bẹrẹ idanwo naa la gbọ pe awọn agbofinro ri i pe aworan ọkunrin naa yatọ si fọto to wa lori iwe pelebe tileeṣẹ to n ri si eto ẹkọ nipinlẹ Ọṣun fun awọn ti wọn waa ṣedanwo naa.
Nigba ti wọn si yẹ orukọ to wa nibẹ wo daadaa ni wọn ri i pe orukọ obinrin ni, ki i ṣe ọkunrin. Bayii ni wọn mu un, ti wọn si fa a le ọlọpaa lọwọ.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, kọmiṣanna feto ẹkọ l’Ọṣun, Họnarebu Fọlọrunṣọ Oladoyin Bamiṣayemi, bu ẹnu atẹ lu iwa ti Arẹmu atiyawo rẹ hu. O ni bawo ni ẹni to fẹẹ maa kọ awọn akẹkọọ ni ẹkọ iwe ati ẹkọ ihuwasi lawujọ yoo ṣe hu iru iwa bẹẹ.
O waa ke si gbogbo awọn ọdọ lati mọ pe wiwa ọna abuja ko pe rara, ṣiṣe iṣẹ takuntakun nikan lo le mu eeyan ṣaṣeyọri.