Stephen Ajagbe, Ilọrin
Lalẹ ana, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrazaq Abdulrahman, ṣabẹwo sileeṣẹ tẹlifiṣan tijọba apapọ, NTA, to wa lagbegbe Fate, niluu Ilọrin, nibi ti ijamba ina ti ba dukia olowo nla jẹ.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aagọ mọkanla alẹ ọjọ Iṣẹgun yii nijamba ina naa ṣẹlẹ. Abdulrazaq pẹlu Kọmiṣanna fun iṣẹ-ode, Onimọ-Ẹrọ Rotimi Iliyasu, ni wọn jọ lọ sibẹ lati wo bi iṣẹlẹ naa ṣe ri atawọn ohun to bajẹ nibẹ.
Ina to ṣadeede ṣẹ yọ ọhun jo awọn ọọfiisi kan ati apa kan lara ọọfiisi igbohun-safẹfẹ. Ko sẹni to mọ pato ohun to ṣe okunfa ina naa.
Ọga agba ileeṣẹ panapana ni Kwara, Waheed Iyanda Yakubu, ṣalaye pe ni nnkan bii aago mọkanla kọja ogun iṣẹju ni wọn tẹ ileeṣẹ naa laago lati fi to wọn leti.
O ni iwadii ṣi n lọ lati mọ ohun to fa ijamba ina naa.