Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Iku to pa dẹrẹba tanka epo diisu kan lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu keji yii, lagbara pupọ, ọkunrin naa jona ku egungun lai si iranlọwọ ti ẹnikẹni le ṣe fun un ni.
Oju ọna Atoyo, beeyan ba n jade kuro n’Ijẹbu-Ode, ni iṣẹlẹ yii ti waye. Ọna marosẹ Ijẹbu-Ode si Ogbere ni.
Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi, Alukoro TRACE, ṣalaye pe ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ku iṣẹju mẹẹẹdogun ni tanka epo diisu naa gbina.
O ni dẹrẹba to wa a ni ko ro ti pe epo loun gbe, ere buruku lo n sa loju ọna yii, nibi to si ti padanu ijanu ẹ niyẹn, ni tanka to n wa ba fẹgbẹ lelẹ.
Bi mọto naa ṣe fẹgbẹ lelẹ ni epo inu rẹ danu, lẹyin to danu naa ni ina sọ.
Dẹrẹba yii nikan lo wa ninu ọkọ naa, bina oun si ṣe sọ lo jo o pa. Ẹnikẹni ko le e ran an lọwọ bo ti wu ko kere to, nitori niṣe ni ina naa n jo geerege titi to fi jo o pa raurau.
Nigba tawọn eeyan yoo fi de ọdọ rẹ, egungun rẹ nikan lo ku to wa nilẹ, ko si kinni kan ti ẹnikẹni tun foju ri lara rẹ mọ.
Koda, ko sẹni to ri nọmba tanka naa mu lẹyin iṣẹlẹ yii, gbogbo ẹ ti jona di eeru.
Amọran nikan lo ku ti TRACE n gba awọn awakọ nla yii, ati awọn ti wọn n wa kekere naa, pe ki wọn yee sare, ki wọn si maa sinmi daadaa ki wọn too gbe mọto sọna fun irinajo, nitori ohun to n ṣọṣẹ ko to nnkan.