Ọlawale Ajao, Ibadan
Awọn agba bọ, wọn ni bíkú ile ò ba pa ni, tòde o le pa ni. Ohun tó ṣẹlẹ si Ọgbẹni Oluwọle Agboọla, àgbẹ̀ aladaa-nla ti awọn ọ̀bàyéjẹ́ yinbọn pa lẹyin ti wọn ji i gbe ninu oko ẹ̀ n’Ibadan laipẹ yii ree.
Awọn Fulani ti Agboọla, ẹni to kẹkọọ gboye gíga nileewe Fasiti Ibadan, ṣugbọn to yan iṣẹ àgbẹ̀ láàyò yii, gba gẹgẹ bíi òṣìṣẹ́ inu oko ẹ̀, to sì pèsè ile fún wọn sinu ọgbà oko nla ọ̀hún lati máa gbe, ni wọn ṣètò bi awọn Fúlàní ẹgbẹ wọn ṣe waa ji i gbé.
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2020 yii, lawọn gende ọkunrin mẹfa kan ti wọn mura bii ọmọ ogun orileede yii ya wọnu oko baba naa to wa lọna Abule Abà-Odò, lagbegbe Mọniya, nilẹ Ibadan, ti wọn si fipa mu un wọ inu igbo lọ niṣeju awọn oṣiṣẹ ẹ.
Ṣaaju ijinigbe ọ̀hún lawọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ ti ranṣẹ pè é pé ọkan ninu awọn ẹlẹdẹ to n sìn ti bímọ mẹ́wàá.
Iroyin ayọ yii lo mu àgbẹ̀ aladaa-nla yii sáré gba oko lọ, pẹlu ọmọkùnrin rẹ̀ láti lọọ mojuto nnkan ọsin rẹ naa pẹlu awọn ọmọ tó bí. Kò mọ pé niṣe ni wọn fi iroyin ẹlẹdẹ to bímọ tan an fún awọn ajinigbe mú.
Ni nnkan bíi aago mẹjọ aabọ ọsan lo débẹ. Nibi to si ti n ṣabẹwo sí àwọn oṣiṣẹ ẹ̀ lọkọọkan nibi iṣẹ ọtọọtọ to fi kaluku wọn sì láwọn ẹrúukú ti wọlé de tibọntibọn. Ibọn nla tàwọn ọlọpaa fi n koju awọn ogbologboo adigunjale lọjọ tójú ogun ba le tan poo.
Lẹyin ti awọn ajinigbe ẹlẹni mẹ́fà tí wọn wọ aṣọ ṣọja wọnyi yinbọn sókè láti kó alakọwe to yan iṣẹ àgbẹ̀ láàyò yii láyà jẹ, ni wọn sáré sí ọkunrin naa, ti wọn sì mú un ni pápá mọ́ra jade kuro ninu ọgbà oko nla ọhun.
Ọjọ keji, lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu naa, lawọn ajinigbe pe awọn mọlẹbi ẹ̀ lati jẹ ki wọn mọ pe ọdọ àwọn lẹni wọn wa, ati pe mílíọ̀nù lọna àádọta Naira (₦50 m) lawọn yóò gba lọwọ wọn ki awọn tóo lè fi í sílẹ.
Ṣugbọn mílíọ̀nù kan ati ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta naira o le mẹ́wàá (N1.650m) lawọn ẹbi rí ṣà jọ. Lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ lawọn ajinigbe gbowo ọhun bẹẹ lọwọ wọn. Lẹyin naa ni wọn fi àwọn ẹbi baba yii lọkan balẹ pé kí wọn máa retí ẹni wọn nigbakuugba sí asiko naa.
Ṣugbọn idile Agboọla kan wulẹ reti reti lasan ni, wọn kò rí ẹni wọn lẹyin ti wọn lọọ gbe owo nla pade awọn Fulani ninu igbo tan.
Ni gbogbo igba naa, awọn ẹbi kò mọ-ọn-mọ fi ọrọ naa lọ awọn ọlọpaa, wọn gba pe àwọn olubi èèyàn náà le pa eeyan awọn bi wọn ba gbọ pe awọn agbofinro ti n wa awọn. Ṣugbọn ọrọ ta a ni ki baba ma gbọ, baba náa ni yóò padà parí ẹ̀. Awọn agbofinro naa ni wọn pada sa lọọ ba nigba ti awọn ọdaju eeyan naa ko tu Agboọla silẹ nigbekun wọn.
Ikọ̀ atọpinpin ti ọga ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, CP Joe Nnwachukwu Enwonwu, gbe dide labẹ akoso CSP Oluṣọla Arẹmu, lo pada ri Agboọla ninu igbo kan ti ko fi bẹ́ẹ̀ jinna sí oko ẹ̀, ṣugbọn o ti kuro l’Agboọla alààyè nigba náà, nítorí àwọn ẹruuku ti pa a, aṣọ to wọ lọjọ ti wọn ji í gbé lọmọ ẹ̀ paapaa fi da a mọ nigba ti awọn ọlọpaa mu un lọ síbi tí wọn ti ri oku naa lati waa wo o boya ti baba ẹ̀ ni.
Inu oko ti wọn ti ji olóògbé gbé lawọn ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ. Ninu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ti wọn ṣe fawọn oṣiṣẹ inu oko naa náà ni wọn ti gbọ pe eyi to n jẹ Dahiru ninu awọn oṣiṣẹ oloogbe naa ti wọn fi ile ti ọkunrin àgbẹ̀ yii pèsè fawọn oṣiṣẹ ninu ọgbà oko naa ṣe ibugbe kò sí nile lati ọjọ mẹta sẹyin.
Iwadii awọn ọlọ́pàá fi hàn pé ọjọ ti wọn sanwo fawọn ajinigbe gan-an ni Dahiru kuro ninu ọgbà oko ọga ẹ̀. Eyi lo sí fu àwọn ọlọ́pàá lára ti wọn fi wa ọkunrin ẹni ọdun marundinlogoji naa kan. Nibi kan nitosi Ojú-Irin, ni Bodija, n’Ibadan, to fara pamọ́ sí ní wọn ti mu un lọjọ kẹta, oṣù kin-in ni, ọdún yii.
Nigba ti wọn fọrọ po o nifun daadaa lo jẹwọ pe oun lọwọ nínú bi awọn Fúlàní ẹgbẹ oun ṣe waa ji ọga oun gbé, ati pé aburo oun ti awọn jọ jẹ ọmọ ìyá, ọmọ baba kan naa, lo ko àwọn ẹruuku ọ̀hún sòdí waa palẹ ọga oun mọ.
Ìyẹn lawọn agbofinro ṣe tẹsiwaju ninu iwadii wọn ti wọn fi mú àwọn meji mi-in ti wọn n jẹ Ahmad Muhammadu ati Ibrahim Mamuda mu.
Ibrahim yii ni wọn lo lọọ gba owo ti awọn ẹbi oloogbe gbe lọ fun awọn ajinigbe naa nínú igbó. Ṣugbọn ọkunrin naa sọ pe oun ko mọ nnkan kan nipa ọran naa bo tilẹ jẹ pe aburo oloogbe fìdí ẹ̀ múlẹ pe oun gan-an lo gba owo ti awọn ajinigbe béèrè lọwọ oun lọjọsi.
Lọjọ kẹwàá, oṣù keji, ọdún 2021 yìí, ti i ṣe Ọ́jọ́rùú, Wẹsidee, to kọja, lọga agba awọn ọlọ́pàá ipinlẹ Ọyọ, CP Ngozi Onadeko, ṣafihan awọn mẹtẹẹta fawọn oniroyin lolu ileeṣẹ wọn to wa l’Ẹlẹyẹle, n’Ibadan.
Ninu ifọrọwọrọ pẹlu akọroyin wa, Dahiru to pera ẹ̀ ni Fúlàní lati ilu Ilọrin, fìdí ẹ̀ mulẹ pé òun ba aburo oun ja gan-an fún bo ṣe ko àwọn ajinigbe sodi waa ji ọga oun gbe, bo tilẹ jẹ pe oun gba ẹgbẹrun lọna àádọta Naira (₦50,000) to fún oun gẹgẹ bíi èyí tí wọn pin kan oun ninu owo ti wọn gba lọwọ awọn mọlebi ọga oun.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Mo wa loko lọjọ ti wọn waa ji ọga wa gbe. Ọga wa ati ọmọ rẹ ni wọn jọ wà soko lọjọ naa. Nibi ti wọn ti n ṣabẹwo sí wa lọkọọkan nibi ti kaluku wa ti n ṣiṣẹ lawọn to waa ji wọn gbe ti waa gbe wọn láàrin aago kan sí meji ọsan. Wọn na awa náà, koda, wọn ti mi sinu odo ẹja.
“Kì í ṣèmi ni mo pe awọn to waa ji wọn gbe wa. Iṣẹ ọwọ aburo mi, Hassan ni. Oun naa ti ba ọga ṣiṣẹ ri. O ti máa n sọ fun èmi àti Muhammad to bá ti wà pe oun fẹẹ ṣètò lati ji ọga wa gbe, a si máa n sọ pé kò má dan an wo.
“Ko sọ fún mi ko tóo ko àwọn èèyàn waa ji oga gbe lọjọ yẹn. Gbogbo awọn to wa pata ni mo da mọ. Abubakar, Aliu, Onto ati Yẹ́lò wa ninu wọn.
Nitori owo ti ko si lọwọ mi lo jẹ kí n kuro loko ti mo fi lọ si igboro lọjọ kokanlelọgbọn oṣu to kọja. Nibi ti mo duro de Hassan si naa lo ti waa ba mi, to fun mi ni ẹgbẹrun lọna àádọta naira (₦50,000). Mo ni owo ki leyi, o ni owo ọga wa ti wọn ji gbe ni. Mo ba a ja, ṣugbọn mo pada gbowo yẹn lọwọ ẹ̀. Mo bèèrè pé owo ti Muhammad da, o sọ pé òun maa waa fún un loko funra oun. Muhammad lo mu awọn ọlọpaa waa ba mi ti wọn fi waa mu mi”.
Ninu ọrọ tiẹ, Muhammad sọ pe oun ko mọ nnkan kan nipa iṣẹlẹ naa, ati pe nnkan ni Dahiru dagbere pe oun fẹẹ lọọ ra n’Ibadan ti ko fi pada sile laarin ọjọ mẹta, ki oun too mu awọn ọlọpaa lọ sí ibi ti oun mọ pé ọ ṣee ṣe ko wà tí wọn fi mu un.
“Ààfáà lémi. Hàǹtú ni Hassan maa n waa mu lọdọ mi ni gbogbo igba to ba wa soko, ko sí figba kankan sọ fún mi pe oun máa ji ọga gbe.
” Yatọ si ẹgbẹrun mẹẹẹdogun Naira (₦15,000) ti ọga máa n fún mi lowo-oṣù, wọn tún máa n fún mi ni ẹgbẹrun kọọkan Naira (₦1,000) ni gbogbo igba ti wọn ba wa soko. Bẹẹ ni wọn tun fún mi ní ilẹ ti mo fi n dáko ninu ọgbà oko wọn ti mo n gbe yẹn. Ṣe ẹni to n ṣe dáadáa sí mi bẹẹ yẹn ni ma a waa sọ pe ki wọn ji gbe. Ki ni mo fẹẹ gba ninu ki aburu ṣẹlẹ sí i”?
Ẹni ọdun mejidinlaaadọta ni Ọgbẹni Oluwole Agboọla nigba ti awọn olubi ẹda yinbọn pa a. Iyawo kan, Abilekọ Funmi Ọnadepo-Agboọla, pẹlu ọmọkunrin mẹta loloogbe náà fi saye wọ kaa ilẹ lọ.
Lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdún yii, nijọ Convenant Church, to wa laduugbo Jericho, n’Ibadan, sinku rẹ nilana isinku onigbagbọ.
Ọga agba ọlọpaa ti fọwọ sọya pe laipẹ lai jinna lawọn yóò mú àwọn afurasi ọdaran yòókù tí wọn lọwọ ninu iku ọkunrin naa, nitori awọn agbofinro ko sinmi iwadii wọn lori iṣẹlẹ yii.