Omiṣore darapọ mọ ẹgbẹ APC l’Ọṣun

Florence Babaṣọla

Igbakeji gomina ipinlẹ Ọṣun nigba kan, to tun ti figba kan jẹ aṣofin to ṣoju awọn eeyan Ifẹ/Ijeṣa nile-igbimọ aṣofin agba, Ọtunba Iyiọla Omiṣore, ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Lasiko ti ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, kede pe ki atundi ibo waye lawọn ijọba ibilẹ mẹrin ninu idibo gomina ipinlẹ Ọṣun to waye lọdun un 2018 ni Omiṣore gba lati ṣiṣẹ papọ pẹlu ẹgbẹ APC, to si ko gbogbo awọn oludibo ẹgbẹ SDP to wa fun un.

Latigba naa lo ti di pe ijọba Gomina Oyetọla n fun ẹgbẹ SDP ni nnkan diẹdiẹ ninu iṣejọba wọn. Wọn ni kọmisanna, oludamọran pataki fun gomina, alaga ijọba ibilẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Amọ ṣa, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni Ọtunba Iyiọla Omiṣore jade sita gbangba pe oun ti fi ẹgbẹ oṣelu SDP silẹ, to si darapọ mọ ẹgbẹ APC. O gba fọọmu ẹgbẹ ni wọọdu idibo rẹ, iyẹn Wọọdu kẹfa to wa ni Mọrẹ, niluu Ileefẹ.

Labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AD ni Omiṣore ti ba Gomina Adebisi Akande ṣiṣẹ gẹgẹ bii igbakeji gomina Ọṣun, ko too di pe wọn yọ ọ nipo lọdun 2002.

O darapọ mọ egbẹ oṣelu PDP, o si di aṣofin agba fun agbegbe Ifẹ/Ijeṣa fun saa meji. O n pinnu lati dije funpo gomina ipinlẹ Ọṣun labẹ ẹgbẹ naa ni wahala bẹ silẹ, to si binu kuro ninu ẹgbẹ pẹlu awọn alatilẹyin rẹ, ti wọn si darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu SDP.

Leave a Reply