Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Bi wọn ba n sọ pe iku ẹnikan ba awọn eeyan lojiji, iku to pa Alaaji Taofeek Adeyinka tawọn eeyan mọ si Tobacco, l’Abẹokuta ni.
Igba ti wọn n sinku ẹ laaarọ Ọjọbọ, ọjọ kejidinlogun, oṣu keji yii, lawọn mi-in too gbagbọ pe gomina awọn onifuji ninu ẹgbẹ FUMAN ipinlẹ Ogun naa ti jade laye loootọ.
Ko si kinni kan to ṣe Tobacco tawọn eeyan tun mọ si Itẹlọrun 1, tẹlẹ.
Ninu ọrọ ti Alhaaji Ishọla Mofọlọrunṣọ Akerele to jẹ Ààrẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ to kawe jade ni St. John’s Anglican High School, Kutọ, l’Abẹokuta, lọdun 1985 si 1986, sọ lo ti fidi ẹ múlẹ̀ pe ẹgbẹ kan inu ni oloogbe naa sọ pe o n run oun laaarọ Ọjọruu, o ni inu naa n fa oun so, o si lọ sọsobitu.
Inu ohun lo run un dalẹ ọjọ naa to fi dagbere faye.
Ọkan ninu awọn akẹkọọ ọdun 1985 si 86 naa ni Oloogbe Tobacco. Akọwe ẹgbẹ wọn, Nurean Bakennẹ, ṣàlàyé pe lati ileewe lo ti n kọ fuji, pupọ ninu awọn maa n gberin lẹyin rẹ nígbà yẹn ko too di pe kaluku gba ọna tirẹ lọ.
O ni bawọn ba fẹẹ ṣe ipejọpọ ọlọdọọdun lẹyin tawọn kúrò nileewe, Tobacco lo maa n waa kọrin fawọn.
O ṣapejuwe ọkunrin tọjọ ori ẹ ko ju aadọta lọ naa bii ọmọluabi tootò, o ni bawọn ẹgbẹ gbogbo to wa yoo ṣe maa ranti rẹ si rere niyẹn.
Iyawo kan, Funmilayọ Adeyinka, aati ọmọ mẹ́ta torukọ wọn n jẹ Taofeekat, Anjọla ati Ọlọrunwa lo fi saye lọ. Ile rẹ to wa n’Ijeun Tuntun, l’Abẹokuta, ni wọn sin in si.
Gbogbo eeyan to mọ Tobacco l’Abẹokuta lo n daro iku rẹ, bẹrẹ latori awọn onifuji, titi kan awọn onijuju atawọn olorin ẹmi, kaluku n sọ pe oninuure lọ.