Faith Adebọla
Ọga agba tẹlẹ fun ileeṣẹ aṣọbode ilẹ wa (Nigeria Customs Service), Ọgbẹni Abdullahi Dikko, to n jẹjọ ẹṣun iwa ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku lọwọ ti dagbere faye.
Ọsan Ọjọbọ, Tọsidee yii, lọkunrin ọmọ bibi ilu Musawa, nipinlẹ Katsina, naa ku lẹni ọgọta ọdun (60) lẹyin ti aisan buruku kan ti n ba a finra fun ọpọ ọdun.
Laarin ọdun 2009 si 2015 loloogbe naa wa nipo ọga agba ileeṣẹ kọsitọọmu, iyẹn lasiko iṣejọba Goodluck Jonathan.
Gẹrẹ to ti kuro nipo naa lawọn ajọ to n gbogbun ti iwa jibiti, ṣiṣe owo ilu mọkumọku, EFCC ati ICPC, ti fẹsun kan an ti wọn si wọ ọ lọ sile-ẹjọ, wọn lo lo ipo rẹ lati ṣe magomago awọn owo to yẹ ko fi jiṣẹ funjọba, ṣugbọn to jẹ apo ara rẹ lowo wọlẹ si. Ori igbẹjọ yii lo wa ti EFCC fi gbẹse le awọn ile rẹ kan, atawọn ọkọ bọginni tọkunrin naa ko jọ.
Ṣugbọn nitori ailera rẹ, ile-ẹjọ yọnda beeli fun un, ko le lọọ gba itọju. Ẹnu beeli ọhun lo wa, ti wọn n sun igbẹjọ siwaju lọpọ igba latari ailera rẹ, kọlọjọ too de yii.