Ijamba ina jo ile awọn akẹkọọ pẹlu ẹru nileewe girama Ọffa

Stephen Ajagbe, Ilorin

 

Awọn ẹru ti ko niye nijamba ina kan to ṣẹlẹ nirọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, jo nileewe girama tilu Ọffa, OGS.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ pe ibugbe awọn akẹkọọ-binrin ni ina naa ti ṣẹ yọ, to si jo yara mẹfa gburugburu lara awọn yara ogun to wa nile alaja kan naa.

Alukoro ileeṣẹ panapana ni Kwara, Ọgbẹni Hassan Hakeem Adekunle, ninu atẹjade kan, ṣalaye pe nnkan bii aago mẹrin aabọ irọlẹ ni awọn gba ipe pajawiri latọdọ ẹnikan torukọ rẹ n jẹ Taiye.

Adekunle ni bawọn oṣiṣẹ panapana ṣe tete debẹ mu ki wọn ri ina naa pa lasiko, bi bẹẹ kọ, ko ba jo gbogbo awọn ogun yara naa patapata.

O niwadii awọn fi han pe aikiyesara ẹnikan to n jo nnkan lo mu ki ina naa ran gba ibugbe awọn akẹkọọ to jona naa.

Ileeṣẹ panapana waa rọ araalu lati maa ṣọra fun ohun to le fa ijamba ina, paapaa lasiko ọgbẹlẹ yii.

Leave a Reply