Ọwọ ti tẹ Emmanuel atawọn ọrẹ rẹ ti wọn n fibọn gba ọkada n’Ileefẹ

Florence Babaṣọla

Iroyin ayọ lo jẹ fun awọn ọlọkada ilu Ileefẹ, nigba ti wọn gbọ pe awọn afurasi ti wọn n fibọn gba ọkada lọwọ wọn ti balẹ sọgba ẹwọn.

Awọn afurasi ọhun ni Muyiwa Abẹrẹijo, to jẹ ẹni ọdun mejidinlogun, Sunday Clement, to jẹ ẹni ọdun marunlelogun, ati Joseph Emmanuel, toun jẹ ọmọ ogun ọdun.

Laaarin osu kin-in-ni ati oṣu keji, ọdun ti a wa yii, la gbọ pe awọn ọdọkunrin naa fi ṣoro bii agbọn niluu Ileefẹ, ṣugbọn lẹyin ọpọlọpọ iwadii, ọwọ agbofinro tẹ wọn, wọn si foju bale-ẹjọ.

Ni kootu, agbefọba, ASP Joseph Adebayọ, ṣalaye pe pẹlu ibọn, ada atawọn nnkan ija mi-in lawọm olujẹjọ mẹtẹẹta fi gba ọkada Bajaj Boxer ti owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ọtalelugba naira (#260,000) lọwọ Ọgbẹni Adeleke Abayọmi.

Bakan naa ni wọn tun gba ọkada Hi Motorcycle ti owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ọtalelugba o din mẹwaa (#250,000) lọwọ ọlọkada kan torukọ rẹ n jẹ Usman Yusuf pẹlu ibọn.

Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn ni igbimọ-pọ huwa buburu, idigunjale ati gbigbe ibọn sakabula kaakiri.

Lẹyin ti wọn sọ pe awọn ko jẹbi gbogbo ẹsun ọhun ni agbẹjọro wọn, Okoh Wonder, bẹ kootu lati fun wọn ni beeli, ṣugbọn adajọ Majisreeti naa, A. A. Adebayọ, sọ pe ile-ẹjọ oun ko lagbara lati gbọ ẹsun idigunjale.

Adebayọ paṣẹ pe ki agbefọba mu ẹda iwe ipẹjọ naa lọ si ẹka to n gbọ ẹsun awọn araalu nileeṣẹ eto idajọ ipinlẹ Ọṣun fun imọran to peye lori ẹ.

O waa paṣẹ pe ki wọn lọọ fi awọn olujẹjọ pamọ sọgba ẹwọn titi ọjọ kẹjọ, oṣu kẹrin, tigbẹẹjọ yoo tun waye lori ọrọ wọn.

Leave a Reply