Ọlawale Ajao, Faith Adebọla
Aṣigangan tilu Igangan, Ọba Abdul-Azeez Adeoye Adewuyi, Aribiyan keji, Gbadewọlu ki-in-ni, ti darapọ m’awọn baba nla rẹ.
ALAROYE gbọ pe ọba alaye naa mi imi ikẹyin laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kejila yii.
Ninu ọrọ ti Alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa gbe soju opo ayelujara fesibuuku rẹ nipa iṣẹlẹ ọhun, Ọnarebu Lateef Akorede ni:
“Pẹlu ẹdun ọkan ni mo fi gbọ ti iṣẹlẹ ipapoda ọba wa, Abdul-Azeez Adeoye Adewuyi, Aribiyan keji, Gbadewọlu ki-in-ni, Aṣigangan tilu Igangan, to waja laaarọ yii. Adanu nla ni iṣẹlẹ yii jẹ fun ilẹ Ibarapa ati gbogbo Yoruba lapapọ.
“A maa ṣaaro ọgbọn yin Sa, bi ẹ ṣe jẹ adari rere, ifẹ tẹ ẹ ni fun ilẹ yii, ati bẹ ẹ ṣe n ṣatilẹyin fun ohunkohun to ba ti jẹ ti Ibarapa, a mọyi yin o.
“Ọba atata ni yin, ifẹ awọn eeyan yin si jẹ yin lọkan.
“Sun un re o.”
Ọsan ọjọ Iṣẹgun yii la gbọ pe wọn yoo sinku ori ade naa n’Igangan, nilana isinku Musulumi.