Aṣọ ati ijẹkujẹ ni mo maa n fowo ti mo ba ri nidii ole jẹ – Andrew

Faith Adebọla, Eko

Afi k’Ọlọrun maa ṣọ wa lọwọ awọn kọlọransi ẹda to kun igboro lasiko yii, tori bawọn ọdaran to n ja ọlọkọ lole ṣe n huwa ibi wọn, bẹẹ lawọn kan tun fi iṣẹ mọto wiwa boju lati fi ja ero ti wọn ba gbe lole, iru wọn ni Andrew Valentino, ẹni ọdun mejidinlogoji, Oluwafẹmi Adesọji, ẹni ọdun mẹrindinlogoji, Micheal Idoko, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, ati Toni Onwoluwe toun jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, to jẹ awọn ero to ba wọ takisi  lawọn maa n ja lole, ṣugbọn ọwọ palaba wọn segi lọsẹ to kọja yii.

Andrew funra ẹ lo ṣalaye pe iṣẹ awakọ takisi loun n ṣe nileeṣẹ Uber l’Ekoo pẹlu mọto ayọkẹlẹ tẹnikan gbe foun pe koun maa dilifa lori rẹ lọsọọsẹ. Mọto ọhun lo ni o yọnu ni nnkan bii oṣu meji sẹyin lagbegbe Ajah, ko si sowo kankan lọwọ oun, igba toun ko si mọ eyi ta a ṣe mọ loun ba jokoo sile ọti kan, ibẹ loun ti pade Micheal Idoko.

O ni Idoko lo beere pe ki lo de toun sorikodo, loun ba ṣalaye fun un. O ni ọkunrin yii lo sọ pe ṣe oun le jẹ ki awọn fi mọto naa wa owo to pọ si i tawọn ba tun un ṣe tan, oun si gba si i lẹnu. N’Idoko ba pe awọn bọis kan lori aago, wọn si tun mọto naa ṣe, o si sanwo fun wọn, ni wọn ba ṣadehun lati pade nile ọti mi-in laarin ọsẹ.

Nigba ti wọn pade ni Idoko ṣalaye pe iṣẹ lawọn n ṣe, ibẹ naa lawọn mẹrẹẹrin si ti mọ ara wọn. O ni bawọn ṣe n ṣe e ni pe ẹni kan lara awọn yoo wa mọto, awọn yoo si ti pin ara awọn si awọn ibudokọ kan loju ọna ibi tawọn ba n gbe ero lọ, lawọn naa yoo ba mura bii ero tootọ. O ni ọpa jaaki dudu gbọọrọ kan bayii ti wa labẹ siiti iwaju lẹgbẹẹ dẹrẹba, Onwoluwe lo maa jokoo siwaju, ti yoo si mu ọpa naa dani.

O ni itosi ibi tawọn meji yooku ba duro si lawọn yoo ti tẹ bireeki ọkọ, ti ẹni to mu ọpa jaaki naa dani yoo si fa a yọ lojiji, ti yoo fi haama kekere kan gba ọpa naa nidii ko le dun bi ibọn tootọ ti wọn ṣẹṣẹ ki, awọn yoo si paṣẹ fun ero naa lati ma ṣe ṣi ori soke rara.

Idorikodo naa lo ni o maa wa tawọn fi maa fipa gba kaadi ẹrọ ipọwo rẹ, awọn yoo si beere fun nọmba ikọkọ to fi n ṣi kaadi naa, o lawọn ti ni ẹrọ kan to maa jẹ ki awọn mọ boya tootọ ni nọmba ikọkọ ọhun ba a mu, ẹyin naa lawọn yoo wọ ero ọhun ju silẹ ninu mọto, tawọn yoo si sa lọ.

Andrew ni lẹyẹ-o-sọka lawọn yoo tete wa ibi kan ti ẹrọ ipọwo ba wa kan, awọn yoo si gba gbogbo owo to wa ninu asunwọn banki onitọhun. Bo tilẹ jẹ pe ko si apa ibi ti wọn ki i ti ṣiṣẹ aburu wọn ọhun l’Ekoo, o ni oju ọna Lekki si Ajah lọwọ awọn ti dunlẹ daadaa, tori gbogbo apade alude agbegbe naa lawọn mọ daadaa lati sa lọ, awọn ki i ṣi ṣiṣẹ lojoojumọ. O ni aṣọ ati ijẹkujẹ loun n fi owo toun ti pa nidii ole jija naa jẹ.

Ṣa, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ ninu atẹjade to tẹ AKEDE AGBAYE lọwọ pe kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Eko ti gbọ sọrọ ọhun, o si ti paṣẹ pe kawọn afurasi naa lọọ wi tẹnu wọn niwaju adajọ laipẹ.

Leave a Reply