Aṣọbode yinbọn lu Moses l’Ọja-Ọdan, nibi ti wọn ti n le awọn onifayawọ kiri

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Ọkunrin kan, Idowu Moses, jokoo sinu ṣọọbu rẹ jẹẹjẹ, l’Ọja-Ọdan, Yewa nipinlẹ Ogun laaarọ oni, Satide,ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹsan-an ọdun 2020, aṣita ibọn tawọn aṣọbode n yin bi wọn ṣe n le awọn onifayawọ kiri si lọọ ba a.  Bẹ ẹ si ṣe n ka iroyin yii lọwọ, ileewosan ti wọn ti n du ẹmi ẹ lo wa.

Ohun ti ALAROYE gbọ ni pe Ọgbẹni Moses ni alaga awọn panẹ-bita l’Ọja-Ọdan, iwaju ile ẹnikan ti wọn n pe ni Baba Israel ni ṣọọbu rẹ wa.

Oun ati ọkan ninu ọmọ ẹgbẹ rẹ ni wọn jọ wa ninu ṣọọbu to fi di pe awọn kọsitọọmu bẹrẹ si i le awọn onifayawọ to n ko apo irẹsi wọlu kiri. Kọsitọọmu kan ti wọn pe orukọ ẹ ni  Jalo, ni wọn lo yinbọn to ba Moses yii, Abdullahi si lorukọ ọga rẹ ti wọn lo ko awọn kọstọọmu naa sodi wa.

Iroyin kan ti a ko ti i fidi ẹ mulẹ tilẹ sọ pe Moses ti dagbere faye nibi ti wọn ti n tọju rẹ naa.

Leave a Reply