Aṣofin Kwara fẹẹ gba ẹbun ironigbara to fun ọmọlẹyin ẹ, o ni ko ṣatilẹyin foun mọ

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Aṣofin kan nipinlẹ Kwara,  Họnọrebu Razaq Owolabi, to n ṣoju Share/Oke-Ode, ti n beere fun ọkọ to pin lakooko to n ṣeto ironilagbara ni nnkan bii oṣu marun-un sẹyin niluu Sharẹ, nijọba ibilẹ Ifẹlodun, lọwọ arabinrin kan, Alaaja Taibat Suleman, fun ẹsun pe ko jẹ oloootọ si i mọ, to si ni ko da ọkọ naa pada, oun ko bun un mọ.

ALAROYE, gbọ pe ni bii oṣu marun-un sẹyin ni Owolabi pin oniruuru nnkan bii ọkọ ayọkẹlẹ, firiiji, maṣinni iranṣọ ati awọn eroja miiran lati fi ṣe iranwọ fawọn eeyan ẹkun idibo rẹ. Alaaja Taibat si jẹ ọkan lara awọn to jẹ anfaani ọkọ ayọkẹlẹ nibi eto ọhun. Ọkọ Mazda ti nọmba rẹ jẹ SHA 786 LB, lo gbe fun un, ṣugbọn ni bayii, Owolabi ti ni ki Alaaja da ọkọ naa pada tori pe ko jẹ oloootọ si oun mọ, to si ni ki awọn ọlọpaa lọọ gba ọkọ naa tori pe o ji i gbe ni.

Nigba ti Alaaja Taibat Suleiman to wa lati wọọdu keji, niluu Share, n ba awọn oniroyin sọrọ, o sọ pe orukọ oun lo wa nibi iwe ọkọ naa, ṣugbọn nigba ti wahala Owolabi pọ lori yoo gba a pada, kò gba a pada, ni oun ṣe lọọ lu ọkọ naa ta, ki oun le fẹdọ lori oronro, ṣugbọn ṣe ni Owolabi pe awọn to ta ọkọ naa fun, to si ni ọja ole ni wọn ra.

O tẹsiwaju pe ohun ti Owolabi ṣe jẹ iyalẹnu, ọkọ to fi ọwọ ara gbe le oun lọwọ lo waa di pe oun ji i gbe ni.

Titi di asiko ta a n ko iroyin yii jọ, ọrọ naa ko ti niyanju tori pe o ti di ọrọ ọlọpaa, ti Owolabi si ni oun yoo gba ọkọ naa pada dandan ni.

 

Leave a Reply