Aṣofin mẹta tun darapọ mọ APC l’Ogun

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Afikun ti ba iye awọn aṣofin to jẹ ọmọ ẹgbẹ APC nileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun. Eyi waye lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji, nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress(ADC) mẹta to wa nile igbimọ naa, iyẹn Ọnarebu Jẹmili Akingbade, Adegoke Adeyanju ati Wahab Haruna, lawọn ko ṣe ADC mọ, APC lawọn fẹẹ maa ṣe bayii. Eyi tumọ si pe ninu aṣofin mẹrindinlọgbọn (26) to so ile-igbimọ aṣofin Ogun ro, mẹẹẹdọgbọn(25) lo to di ọmọ ẹgbẹ APC bayii, ẹni kan ṣoṣo to ku lo jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Ninu ijokoo ile aṣofin naa to waye lọfiisi wọn l’Oke-Mosan, ni Abẹnugan ile, Ọnarebu Ọlakunle Oluọmọ, ti ka lẹta tawọn ọmọ ẹgbẹ mẹta yii kọ lati fi kede pe awọn ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Onigbaalẹ.

Oluọmọ sọ pe awọn mẹtẹẹta naa darapọ mọ APC ki wọn le sa ipa wọn fun ilọsiwaju ipinlẹ Ogun. Wọn tun sọ pe ija abẹnu wa ninu ẹgbẹ tawọn ti kuro, awọn si ti ba awọn aṣaaju awọn sọ ọ kawọn too gbe igbesẹ lati darapọ mọ ẹgbẹ Onitẹsiwaju ti i ṣe APC.

Lọjọ yii naa ni wọn mẹnu ba ipo to ba ni lọkan jẹ ti papa iṣere Mudal Lawal to wa ni Aṣero, l’Abẹokuta, wa. Awọn aṣofin sọ pe papa iṣere ti wọn fi n ranti Oloogbe Muda Lawal to jẹ ọkan pataki agbabọọlu fun Naijiria ko ṣee ri mọ rara, o si yẹ kijọba Gomina Dapọ Abiọdun ṣe igbedide rẹ kia, nitori akọni ti wọn fi sọri rẹ, ati nitori anfaani to yẹ ko maa ti ibẹ jade.

Ṣa, ile fẹnu ko si pe ki ileeṣẹ to n ri si ere idaraya ati ọrọ awọn ọdọ, mu ẹda iwe ilẹ (survey) papa yii wa, ki wọn si pese akọsilẹ orukọ awọn to n ta ọja tabi ni ile okoowo ninu ọgba naa, ki kaluku le ṣe ẹtọ ẹ nipa sisanwo to ba yẹ ki wọn maa san fun ibi ti wọn ti n ṣòwò yii.

Wọn ni ki wọn gbe iwe owo to wọle lati papa iṣere naa lati ọdun 2015 titi di asiko yii jade, ki ile le mọ iye to wọle ati iye ti wọn na sita nibẹ.

Leave a Reply