Aṣofin PDP gboṣuba fun Oyetọla lori sisan owo-oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Aṣofin to n ṣoju awọn eeyan Obokun/Oriade nile-igbimọ aṣofin apapọ orileede yii, Ọnarebu Oluwọle Ọkẹ, ti sọ pe Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, yẹ lẹni teeyan gbọdọ gboriyin fun lori bo ṣe fọwọ si sisan owo-oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ ijọba.

Ninu atẹjade kan ti Wọle Ọkẹ fi sita lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lo ti ni loootọ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP loun, ṣugbọn oṣelu ko sọ pe keeyan dibọn bii ẹni pe oun ko ri iṣẹ rere ti ẹni to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu mi-in ba n ṣe.

Ọkẹ ṣalaye pe ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nikan lo jẹ oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ọṣun, gbogbo awọn to wa ninu ẹgbẹ oṣelu atawọn ti ko ṣe oṣelu ni.

Nitori naa, fun gomina lati gbe igbeṣe naa lasiko yii, to si tun gbẹsẹ kuro lori bi wọn ki i ṣe san afikun owo-oṣu oṣiṣẹ lọdọọdun, aṣofin yii sọ pe iwuri nla ni.

O ni oun fẹ igbesi aye irọrun fun gbogbo awọn eeyan toun n ṣoju l’Abuja, ohunkohun ti ẹnikẹni ba si ṣe lati fi mu inu awọn araalu dun, lai ka ti ẹgbẹ oṣelu si, yẹ ni igboriyin fun.

O waa gba Gomina Oyetọla niyanju pe ohun to ku tijọba rẹ le ṣe lati mu ki alaafia ati ifọkanbalẹ wa l’Ọṣun ni pe ko tete gbe igbesẹ lori ipese iṣẹ to to ẹgbẹrun lọna aadọta fun awọn ọdọ.

O ni iye awọn ọdọ ti wọn kawe, ṣugbọn ti wọn ko riṣẹ fi ṣe pọ pupọ, ojoojumọ ni wọn si n pọ si i, ko si si bi awọn adari ṣe le ni ifayabalẹ lai ṣe pe awọn ọdọ niṣẹ gidi lọwọ.

Opin ọsẹ to kọja ni Gomina Oyetọla kede pe ijọba oun yoo bẹrẹ sisan owo-oṣu tuntun, iyẹn ẹgbẹrun lọna ọgbọn fun oṣiṣẹ to kere julọ l’Ọṣun, sisan rẹ yoo si bẹrẹ loṣu kọkanla ti a wa yii.

Leave a Reply