Aṣiṣe nijọba wa ṣe lati yan awọn alakooso garaaji rọpo oloye NURTW- Makinde

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin ti ile-ẹjọ ti fagi le eto ìṣàkóso awọn garaaji ti ijọba Gomina Ṣeyi Makinde tìpínlẹ̀ Ọyọ ṣe, ninu eyi to ti yan awọn to wu u lati maa gbowo lọwọ awọn awakọ kaakiri garaaji gbogbo nipinlẹ naa, gomina naa ti jẹwọ pe aṣiṣe gbaa nigbesẹ ọhun jẹ.

Ninu eto ìbáráàlú-sọ̀rọ̀ ti Gomina Makinde máa n ṣe ni BCOS ti i ṣe ileeṣẹ tẹlifiṣan ijọba ipinlẹ Ọyọ lóṣù mẹta mẹta lo ti sọrọ naa lọjọ Àbámẹ́ta, Sátidé, to kọja.

Tẹ o ba gbagbe, lọsẹ to kọja nile-ẹjọ fagi le eto iyansipo awọn alakooso garaaji, eyi ti ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe lati maa gbowo ita lọwọ awọn awakọ.  Onídàájọ M.A. Adegbọla sọ pe owo ti awọn aṣoju ijọba naa n gba lọwọ awọn onimọto kaakiri garaaji gbogbo nipinlẹ naa ko bofin mu rara.

Alaga tẹlẹ fun NURTW ti i ṣe ẹgbẹ awọn awakọ ni ipinlẹ Ọyọ, Alhaji Abideen Ọlajide, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Ejiogbe, lo pẹjọ ta ko bi ijọba ṣe gbẹsẹ le ẹgbẹ NURTW, to si yan awọn mi-in rọpo oun atawọn igbimọ to n ṣakoso ẹgbẹ naa.

O waa rọ ile-ẹjọ lati fagi le igbesẹ ijọba, ko si da ẹgbẹ awakọ ti oun jẹ alaga fun pada saaye ẹ gẹgẹ bo ṣe wa ṣaaju iyansipo Makinde gẹgẹ bii gomina ipinlẹ naa.

Bi Onidaajọ M.A. Adegbọla ṣe fagi le títú ti ijọba tu ẹgbẹ awakọ ka ninu idajọ ẹ lọsẹ to kọja, l’Ejiogbe atawọn eeyan ẹ ti n fo fáyọ̀.

Nigba to n sọrọ lori idajọ naa, Gomina Makinde sọ loju gbogbo aye pe “a ti fara mọ idajọ kootu. A si ti pa awọn alaga ijọba ibilẹ laṣẹ lati gbakoso awọn ibudoko gbogbo nijoba ibilẹ kaluku wọn.

“Lati igba ti ijọba ẹgbẹ NURTW ti n tọwọ awọn kan bọ ṣọwọ awọn mi-in nipinlẹ Ọyọ, eyi nigba akọkọ ti eto yẹn waye to jẹ pe ko la wahala ati ipaniyan lọ. Ilana ta a ti fi lélẹ̀ yìí la oo sì rí i daju pe a n tẹle lọ fún ààbò ẹni ati dukia.”

 

 

Leave a Reply