Aṣiri ọga ileewe to n fipa ba awọn akẹkọọ rẹ lo pọ tu n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Aṣiri ọga ileewe girama Hassanat Islamic College, Tankẹ, niluu Ilọrin, ijọba ibilẹ Guusu Kwara, Ọgbẹni Samuel Aremu (a.k.a. Ọgbẹni Owonikoko), ẹni ọdun mejilelọgbọn, to n fipa ba awọn ọmọ ileewe lo pọ tu, lo ba kọwe fipo rẹ silẹ.

ALAROYE gbọ pe o pẹ ti afurasi yii ti maa n fipa ba awọn akẹkọọ rẹ ati awọn agunbanirọ lasepọ ko too di pe aṣiri rẹ tu. Wọn ni ni kete tawọn ọmọleewe ba ti bọ si ipele to ga (Senior classes), ni yoo ti maa fipa ba wọn lopọ ninu ọfiisi, ati nita ileewe.

Ọkan lara awọn ọmọ to fipa ba lo pọ Haleema, sọ pe gbogbo igba ni ọga ileewe naa, Ọgbẹni Aremu, maa n fi ọwọ ro oun loju ara, bakan naa lo tun maa fẹnu ko oun lẹnu ni ọfiisi rẹ ati nita ileewe lẹyin tawọn ba jade.

Wọn ni Arẹmu kọkọ jiyan ẹsun naa, to si n dunkooko pe awọn ọmọ tọrọ kan ko gbọdọ da awọn oluwadii lohun mọ. Lẹyin ti iwadii pari lo jẹwọ pe loootọ loun n fipa ba Raheema lasepọ, ati pe ki i ṣe oun nikan, o tun darukọ awọn miiran to n fipa ba lo pọ bii: Titilayọ, Fasilat, ati Rọbiat.

Nigba ti  Arẹmu n jẹwọ, o ni ko tiẹ ye oun mọ, o da bii ki oun pa ara oun, o waa ni ki gbogbo awọn mẹjẹẹjọ toun ti fipa ba lo pọ dariji oun, ki wọn maa tu aṣiri naa sita.

Iwadii fidi ẹ mulẹ pe Igbakeji ọga ileewe naa, Ọgbẹni Victor, ti rawọ ẹbẹ pe ki wọn bo aṣiri ọga ileewe yii ni gbogbo ọna, ki wọn ma jẹ ki ọrọ naa lu sita.

Ni bayii, ọga ileewe naa ati igbakeji rẹ ti fiṣẹ silẹ, bo tilẹ jẹ pe awọn alaṣẹ ileewe ọhun sọ pe awọn ko da a duro lẹnu iṣẹ.

 

Leave a Reply