Adewale Adeoye
Ileeṣẹ ọlọpaa orileede wa ti fọwọ ofin mu Ọgbẹni Ahmed Mohammed, to ti figba kan jẹ ọmọ oju ogun ofurufu orileede wa, ẹka tipinlẹ Kaduna, ati ọrẹ rẹ kan, Ọgbẹni Mushiri Abubarkar, ẹsun ti wọn ka sawọn mejeeji lẹsẹ ni pe awọn ni wọn n ta ohun eelo ati ohun ija oloro fawọn oniruuru ikọ agbebọn atawọn afẹmiṣofo to n da wahala silẹ nipinlẹ Zamfara.
ALAROYE gbọ pe ko ju nnkan bii ọdun marun-un lọ ti Ahmed darapọ mọ ọmọ ogun oju ofurufu ilẹ wa tawọn alaṣẹ naa fi gba iṣẹ lọwọ rẹ, nitori to ṣẹ sofin orileede yii. Latigba naa si ni Ahmed ti lẹdi apo pọ pẹlu ọrẹ rẹ, Abubakar, tawọn mejeeji si n ta ohun eelo tawọn ọmọ ogun orileede yii n lo fawọn oniṣẹ ibi gbogbo ninu igbo, ko too di pe ọwọ tẹ wọn logunjọ, oṣu Kejila, ọdun 2023 to kọja yii, nijọba ibilẹ Shinkafi, nipinlẹ Zamfara.
Ṣe ni Ahmed maa ko awọn ohun eelo ọhun fun ọrẹ rẹ, Ọgbẹni Abubarkar, ti iyẹn aa si ko o lati ipinlẹ Kaduna lọọ fawọn agbebọn ọhun ninu igbo nipinlẹ Zamfara.
Lara awọn ohun eelo awọn ọmọ ogun orileede yii tawọn ọlọpaa gba lọwọ awọn ọdaran ọhun lasiko ti wọn n ko o lọ ni oniruuru aṣọ awọn ọmọ ogun, fila, kadigaani, ṣẹẹti penpe tawọn ṣọja maa n wọ sabẹ aṣọ wọn, bẹliiti ṣoja ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa orileede yii, Ọgbẹni Muyiwa Adejọbi, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, niluu Abuja, ti i ṣe olu ilẹ wa sọ pe, ‘Ni nnkan bii aago mejila aabọ ọsan ogunjọ, oṣu Kejila, ọdun to kọja yii, ni ikọ awọn ọlọpaa kan ṣakiyesi pe ohun eelo awọn ọmọ ogun orileede yii kan lawọn oniṣẹ ibi ọhun n ko lati ilu Kaduna lọ sipinlẹ Zamfara. Wọn beere ọrọ lọwọ awọn mejeeji, ṣugbọn wọn ko ri esi gidi wi si i, ni wọn ba fọwọ ofin gba wọn mu loju-ẹsẹ. Iwadi ta a ṣe nipa awọn ọdaran ọhun ni ẹri to daju daadaa wa pe ọjọ ti pẹ ti wọn ti n ta awọn ohun eelo ọhun fawọn agbebọn kan to n da alaafia ipinlẹ Zamfara ru. Ọkan pataki lara awọn oniṣẹ ibi ti wọn n ta awọn ẹru ofin ọhun fun ni Ọgbẹni Bello Turji, tawọn alaṣẹ ijọba orileede yii n wa nitori bo ṣe n gbẹmi awọn alaiṣẹ gbogbo laarin ilu.
Ọmọ oju ogun ofurufu ilẹ wa ni Ọgbẹni Ahmed Mohammed tẹlẹ, ṣugbọn awọn alaṣẹ ijọba orileede yii gbaṣẹ lọwọ rẹ nitori awọn iwa radarada kan ti wọn ba lọwọ rẹ, ko ju nnkan bii ọdun marun-un lọ to fi ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ ologun orileede yii ko too di pe wọn le e danu.
Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa orileede wa ti ṣeleri pe awọn ko ni i kaaarẹ ọkan lojuna lati gbogun ti awọn ọdaran gbogbo nilẹ wa, paapaa ju lọ, awọn to n ṣatilẹyin fawọn ọdaran gbogbo to n da alaafia ilu laamu.