Wọn ti mu awọn to n rọ ibọn atawọn ohun ija oloro fawọn afẹmiṣofo

Adewale Adeoye

Ikọ  awọn ọmọ ogun orileede yii kan ti wọn n pe ni ‘Operation Safe Haven’ to wa nijọba ibilẹ Magnu, nipinlẹ Plateau, ti fọwọ ofin mu awọn ọbayejẹ kan to jẹ pe ṣiṣe ohun ija oloro bii ibọn atawọn nnkan  mi-in bẹẹ lawọn maa n ṣe fawọnagbebọn. Oniruuru ohun ija oloro ni wọn ba lọwọ wọn nile kekere kan ti wọn n lo fun iṣẹ ibi ọhun.

ALAROYE gbọ pe owuyẹ kan ti wọn mọ nipa iṣẹ laabi ti awọn ọdaran ọhun n ṣe ni wọn lọọ fọrọ ọhun to awọn ṣoja leti, tawọn yẹn si lọọ fọwọ ofin mu wọn.

Atẹjade kan ti ileeṣẹ ologun orileede yii, ẹka ti agbegbe naa, fi sita lori iṣẹlẹ ọhun l’Ọjọruu, Wesidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, ni wọn ti fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin pe awọn ti fọwọ ofin mu Ọgbẹni Tapshak Plangi, ti i ṣe ọkan pataki lara awọn oniṣẹ ibi ọhun.

Ṣugbọn ẹni to nileeṣẹ ti wọn ti n ṣe awọn nnkan ija oloro ọhun, Ọgbẹni Nuhu Meshack, ti sa lọ patapata.

Atẹjade ọhun lọ bayii pe, ‘Lojuna lati kapa gbogbo awọn oniṣẹ ibi ti wọn n gbe ninu ilu naa, ikọ ọmọ ogun orileede yii ti wọn n pe ni ‘Operation Safe Haven’, ti lọ saarin ilu, wọn ri ile kan to jọ pe wọn n lo fun iṣẹ ibi, nigba ta a dele ọhun, a ṣakiyesi pe awọn kan lo n lo ile naa lati fi rọ ibọn atawọn ohun ija oloro fawọn ọdaran.

Lara awọn ohun ija oloro taa ba nibẹ ni awọn ibọn agbelẹrọ to pọ daadaa to jẹ pe ninu ile naa ni wọn ti ṣe e, ọta ibọn, ibọn ilewọ kekere to pọ daadaa, oniruuru ohun eelo tawọn ọdaran naa n lo lati fi ṣe awọn nnkan ija oloro ọhun.

A ti fọwọ ofin mu awọn ta a ba nibẹ, a si ṣeleri pe a maa too foju gbogbo wọn bale-ẹjọ, ki wọn le jiya ẹṣẹ ohun ti wọn ṣe yii.

 

Leave a Reply