Dada Ajikanje
Ni kete ti ọwọ ti tẹ ọkan lara awọn oṣiṣẹ Oloogbe Dapọ Ọjọra ti wọn sọ pe o yinbọn para ẹ, ni ẹru ti n ba awọn mi-in ti wọn sunmọ ọn, ki awọn ọlọpaa ma baa mu wọn wi pe wọn ni aroye i ṣe lagọ wọn.
Lọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii ni iroyin iku ọkunrin naa gbode kan, ohun ti awọn eeyan si n sọ kiri ni pe funra Dapọ lo yinbọn para ẹ.
ALAROYE gbọ pe ọrọ ti wọn n gbe kiri yii ba awọn eeyan ẹ ninu jẹ gidi, eyi to mu wọn ranṣẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa l’Ekoo lati tọpinpin ohun to ṣẹlẹ gan-an.
Ni kete tawọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii wọn, ẹnikan to ti n ba a ṣiṣẹ lati nnkan bi ọdun mẹrindinlogun sẹyin ni wọn kọkọ mu, bẹẹ ẹni yii gan-an lo kọkọ ri oku arakunrin naa ninu agbara ẹjẹ ẹ, latigba naa lo si ti wa lọdọ awọn ọlọpaa nibi to ti n ṣalaye ohun to mọ gan an.
Yatọ si eyi, ohun ti a tun gbọ ni pe nibi ti wọn ti ba ọkunrin yii, ati bi ọta ibọn ṣe fọn kiri ilẹ tọka si i pe iku ẹ lọwọ kan abosi ninu pẹlu bi wọn ti ṣe kọkọ n gbe e kiri wi pe oun gan-an lo yinbọn fun ara ẹ lori.
Bi iwadii ọhun ṣe bẹrẹ niyẹn o, eyi gan-an ni wọn lo ko wahala ba awọn eeyan ti wọn sun mọ ọn, paapaa awọn ti wọn jọ n ṣe wọle-wọde, ti wọn fi n wo o wi pe wahala to de ba ẹni to ti fi ọdun mẹrindinlogun ṣiṣẹ pẹlu ẹ yii n bọ waa kan awọn naa laipẹ.
Ṣa o, bi awọn eeyan kan ṣe n sọ pe iku ẹ lọwọ ninu, bẹẹ lawọn mi-in ṣi n tẹnu mọ ọn pe okoowo ọkunrin naa ti ko lọ deede mọ, ati iporuru ọkan to ba a latigba tiyawo ẹ ti kọ ọ silẹ ṣee ṣe ko mu un gbẹmi ara ẹ gẹgẹ bi wọn ti ṣe n gbe ọrọ ọhun kiri tẹlẹ.