Lẹyin ọmọ meje, Pasitọ Paul jawee funyawo ẹ, niyẹn ba ni gbogbo ọmọge ijọ lo ti ba sun tan

Faith Adebọla, Eko

Afi bii ere ori itage lọrọ awọn tọkọ-taya ojiṣẹ Ọlọrun kan, Pasitọ Paul Ekwe, ẹni ọdun mọkandinlaaadọta, atiyawo ẹ, Ẹfanjẹliisi Chinwe Ekwe, ni kootu kọkọ-kọkọ to wa n’Igando lọjọ Aje, Mọnde, pẹlu bawọn mejeeji ṣe n fi ẹsun kan ara wọn, ti ọkọ naa si n bẹbẹ pe kile-ẹjọ fopin si igbeyawo wọn.

Pasitọ Paul, to loun ni oluṣọ-aguntan ijọ ajihinrere kan l’Ekoo, lo pe iyawo ẹ lẹjọ, o ni obinrin naa fẹẹ pa oun, ko baa le fẹ ọkọ mi-in, igbeyawo oun pẹlu rẹ ko wọ mọ tori ifẹ ẹ ti yọ lọkan oun, oun ko fẹ ẹ mọ.

Lara ẹsun to tun fi kan iyawo rẹ ni pe ki i gbọran soun lẹnu, ki i si i tẹle aṣẹ toun ba pa, o ni alagidi ati a-ṣe-tinu-ẹni ẹda kan ni. Baale ile naa lo ti kẹyin awọn ọmọ soun debii pe wọn ki i gbọ toun gẹgẹ bii baba wọn mọ. Ojumọ kan, ija kan, ojumọ kan, ẹjọ kan nigbe aye awọn, o si ti su oun pata.

Nigba ti wọn ni kiyawo naa fesi si ẹsun tọkọ ẹ fi kan an, o ni irọ gbuu ati awawi lawọn ẹsun ọhun, o ni bawo loun ṣe maa fẹẹ pa ọkọ toun bi ọmọ meje fun lati aarọ ọjọ aye oun, o lọkunrin naa fẹẹ mọ-ọn-mọ ba oun lorukọ jẹ ni.

Ni idakeji, Chiwen ni pẹlu amumọra gidi loun fi n ba ọkọ naa gbe, iwa agbere lo n fi iṣẹ iranṣẹ ẹ ṣe, gbogbo awọn ọmọbinrin inu ṣọọṣi lo ti fẹẹ ba sun tan, oju maa n gba oun ti fọkọ oun ni ninu ijọ pẹlu bi aṣiiri iwa agbere ẹ ṣe n tu soun lọwọ loriṣiiriṣii.

O nigba kan wa tọkọ oun fọlọpaa mu oun, to loun ji miliọnu marun-un naira mọ oun lọwọ, bẹẹ irọ lo n pa. Igba kan tun wa to gbe ale ẹ waa ka oun mọle, to loun fẹẹ ṣe itusilẹ fun un, bẹẹ agbere ni wọn jọ ṣe. O ni ko bikita fun idile ẹ mọ, ki i gbọ bukaata, ṣugbọn o le ra oriṣiiriṣii ẹbun ati ounjẹ fawọn to n gbe kiri.

Wọn beere lọwọ obinrin naa pe ṣe o fẹ kile-ẹjọ tu igbeyawo wọn ka gẹgẹ bii ẹbẹ ọkọ ẹ, obinrin naa loun kọ ọkọ oun.

Aarẹ kootu naa, Ọgbẹni Adeniyi Kọledoye, paṣẹ pe kawọn mejeeji pada wa si kootu naa lọjọ kọkandilogun, oṣu kin-in-ni, ọdun to n bọ,  ti igbẹjọ yoo ma tẹsiwaju.

Leave a Reply