Aṣọ ọlọpaa ati ti ṣọja lawọn agbebọn yii n wọn fi ṣọṣẹ

Monisọla Saka

Awọn agbebọn ti wọn n da awọn araalu, kaakiri ipinlẹ Anambra laamu ti tun gbọna mi-in yọ. Aṣọ ọlọpaa ati tawọn ologun ni wọn n ran jọ sinu igbo, ti wọn si n lo o lasiko ti wọn ba fẹẹ pitu ọwọ wọn.

Aṣiri awọn olubi ẹda yii tu lẹyin tawọn ẹṣọ alaabo ya wọ inu igbo kan niluu Ifite Ogbunike, nijọba ibilẹ Oyi, nipinlẹ naa. Nibẹ ni wọn ti ri ibi tawọn janduku ẹda ọhun fi ṣebugbe, ti wọn si ti maa n jade lọọ ṣakọlu sawọn eeyan kaakiri awọn ilu ati agbegbe naa.

Lara awọn nnkan ti wọn ri nibẹ ni maṣinni iranṣọ nla, aṣọ ọlọpaa ati ti ṣọja ti wọn ti ran kalẹ, ounjẹ loriṣiiriṣii atawọn nnkan eelo idana. Bakan naa ni awọn oogun abẹnu gọngọ ti wọn n lo lati fi daabo bo ara wọn ko gbẹyin.

Wọn ni ohun to daju ni pe lẹyin tawọn ẹṣọ alaabo tu awọn eeyan yii ka ni awọn ibi ti wọn fara pamọ si lawọn inu igbo to wa lagbegbe Lilu, Orsumoghu, nijọba ibilẹ Ihiala, ni wọn ko wa si agbegbe Ogbunike. Wọn ni ibi tawọn agbebọn yii fi ṣe ibugbe ko fi bẹẹ yatọ si isọ awọn telọ, pẹlu awọn maṣinni iranṣọ atawọn ìrépé aṣọ kitikiti to kun ilẹ nibẹ.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ yii, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Anambra, Tochukwu Ikenga, ṣapejuwe bi wọn ṣe ri ibuba awọn eeyan yii bii aṣeyọri nla kan ninu ogun tawọn n gbe ti iwa ọdaran ati ilakaka awọn lati sọ ọ di ọrọ itan nipinlẹ Anambra.

“Lẹyin olobo tawọn eeyan ipinlẹ Anambra ta ileeṣẹ ọlọpaa, a ti ṣawari diẹ ninu awọn ibi tawọn ọdaran naa n fara pamọ si. Laaarọ kutukutu ni awọn agbofinro ti wọn wa lẹka awọn ikọ ayarabiaṣa, Rapid Response Squad, niluu Akwuzu, ya wọ ibuba kan lagbegbe Ifite, Ogbunike, nijọba ibilẹ Oyi, lasiko ti wọn fẹẹ gba awọn eeyan meji kan ti wọn ji gbe silẹ la.

Meji ninu awọn eeyan ti wọn dihamọra ogun ọhun lawọn ọlọpaa pa. Bakan naa ni wọn tun gba ọkọ ayọkẹlẹ Lexus SUV, pẹlu ọpọlọpọ aṣọ ileeṣẹ ologun to jẹ tawọn ọlọpaa ati tawọn ṣọja”.

O ni loju-ẹsẹ lawọn ẹṣọ alaabo ti kọju ija sawọn atilaawi, ti wọn si pa marun-un ninu wọn lẹyẹ-o-sọka. Ibọn alayinyipo nla AK-47 mẹrin, rọkẹẹti, ọpọlọpọ ọta ibọn, fila ọlọpaa, oogun abẹnu gọngọ atawọn ẹru ọdaran mi-in, ni wọn gba lọwọ wọn”.

O ni eleyii ko ba ma ti rọrun, ti ki i baa ṣe ifọwọsowọpọ awọn agbofinro, awọn ologun, awọn fijilante atawọn ẹṣọ alaabo mi-in, to mu ki ija lati gbogun ti awọn ajinigbe nipinlẹ naa maa gbe pẹẹli si i.

O ni aṣeyọri nla lo jẹ fawọn pẹlu bawọn ṣe dabaru ete wọn lati lọọ ṣakọlu si apa ibi kan nipinlẹ naa. O waa rọ awọn eeyan lati ṣe iranwọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, ki wọn si ran awọn ileeṣẹ eto aabo yooku lọwọ lati tubọ mu ipinlẹ naa pada bọ sipo.

 

Leave a Reply