Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ti sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣi n ṣe akojọpọ awọn iwa itapa sofin tawọn to n beere orilẹ-ede Yoruba, hu lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii. O ni laipẹ lawọn yoo foju gbogbo ẹ han sita.
Satide, ọjọ kin-in-ni, oṣu karun-un, ọdun 2021, ti iwọde awọn to n beere fun ilẹ Olominira Yoruba waye l’Abẹokuta ni Oyeyẹmi sọrọ naa, iyẹn lẹyin ti wọn ni awọn ajijagbara naa kọ lu kọmandi ọlọpaa l’Eleweeran, ti wọn si kọju ija sawọn agbofinro to wa lẹnu iṣẹ.
Ẹ oo ranti pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun lo kọkọ fi atẹjade ikilọ sita fawọn oluwọde naa, pe wọn ko gbọdọ jade lọjọ kin-in-ni, oṣu karun-un, ti wọn tun lawọn yoo ṣewọde.
Awọn ọlọpaa sọ pe iwọde mẹta ti wọn ti ṣe nipinlẹ Ogun tẹlẹ ko mu alaafia wa, afi titẹ ofin loju. Wọn ni ki wọn ma dabaa lati tun un ṣe l’Abẹokuta.
Ṣugbọn ọjọ keji tawọn ọlọpaa ṣekilọ naa lawọn ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oduduwa ti kọ lẹta si wọn pada, ti wọn ni awọn yoo wọde l’Abẹokuta, ko si si ọlọpaa kan ti yoo da awọn lọna, wọn ni dandan ni ominira Yoruba tawọn n beere fun, ipolongo ẹ lai tẹ ẹtọ ẹnikẹni loju lawọn si fẹẹ ṣe.
Bo ṣe di ọjọ Satide naa lawọn ọlọpaa ti lọ si Aafin Alake, nibi tawọn ajijagbara naa ni awọn yoo kora jọ si. Ẹgbẹ Ilana Ọmọ Yoruba ati ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni Ọmọ Koootu-oo-jiire Ọmọ Yoruba Atata ni wọn jọ wọde pọ, ti wọn wọṣọ ibilẹ oriṣiiriṣii.
Mọkanla ninu awọn to waa ṣewọde naa lawọn ọlọpaa ko niwaju aafin Alake ilẹ Ẹgba, ti wọn ko wọn lọ si Eleweeran. Wọn ni wọn huwa to lodi sofin to si le da alaafia ilu ru.
Bi wọn ṣe ko wọn lọ ni awọn yooku ti wọn jọ n wọde lawọn ko ni i gba, wọn si bẹrẹ si i kọrin ijangbara bi wọn ṣe n lọ si kọmandi ọlọpaa, ni Eleweeran. Wọn ni wọn doju ija kọ awọn ọlọpaa to wa lẹnu iṣẹ, wọn si n beere fun idasilẹ awọn eeyan wọn pẹlu tulaasi.
Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Edward Ajogun, lo paṣẹ pe ki wọn fi awọn ti wọn ko naa silẹ, awọn ọlọpaa si yọnda wọn pe ki wọn maa lọ. Ṣugbọn ohun ti a gbọ ni pe bawọn eeyan naa ṣe n jade kuro ni Eleweeran ni wọn bẹrẹ si i ba awọn patako ipolongo ibo to wa loju popo jẹ, iyẹn lagbegbe Ọbantoko.
Wọn ni bi wọn ṣe di Moore Junction, ni wọn ri awọn ọlọpaa kan lẹnu iṣẹ, bi wọn ṣe tun doju ija kọ wọn niyẹn.
Iro ibọn ati taju-taju ni wọn lo gba gbogbo agbegbe naa kan, bẹẹ lawọn to ni ṣọọbu nibẹ sare palẹmọ, ti awọn olugbe adugbo naa si sa wọle lọ.
O ṣe diẹ ki rogbodiyan naa too rọlẹ gẹgẹ ba a ṣe gbọ, eyi lo si fa a ti alukoro ọlọpaa Ogun ṣe ni didakẹ tawọn dakẹ fawọn ajijagbara naa ki i ṣe ti ojo, bi ko ṣe lati ma da alaafia ilu ru, ki arufin ma si maa pọ si i.
Oyeyẹmi kilọ pe awọn eeyan naa gbọdọ ki ọwọ ọmọ wọn bọṣọ, ki wọn ma ro pe bi ọlọpaa ṣe n tẹle ofin ni wọn ko le doju ija kọ wọn pada. O ni akojọpọ gbogbo iwa to lodi sofin tawọn eeyan yii hu lawọn n ṣe lọwọ, ileeṣẹ ọlọpaa yoo si gbe e jade laipẹ, ti gbogbo eeyan yoo ri i.
Ṣugbọn laaarọ ọjọ Satide naa ni Akọwe ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, Maxwell Adelẹyẹ, ti fi atẹjade sita pe mẹẹẹdọgbọn ninu awọn ọmọ ẹgbẹ awọn lawọn ọlọpaa ko, o ni Wasiu Iyanda, Makanjuọla Adigun atawọn mẹtalelogun mi-in lawọn ọlọpaa ko pamọ si Eleweeran. Bẹẹ, o lawọn ko fajangbọn, iwọde wọọrọwọ lawọn ṣe.
Ṣe o ti tojọ mẹta tawọn eeyan kan ti dide pẹlu oriṣiiriṣii orukọ, ti wọn ni Yoruba gbọdọ kuro lara Naijiria, nitori iyanjẹ to foju han kedere lo ti n ṣẹlẹ si ẹya yii latọdun pipẹ wa. Ọkan ninu awọn ẹgbẹ naa ni Ilana Ọmọ Oodua yii, eyi ti Ọjọgbọn Banji Akintoye jẹ olori wọn.
Iwọde ijangbara naa ti waye kaakiri awọn ipinlẹ kaakiri, o ti waye l’Ajuwọn ati Ṣagamu, nipinlẹ Ogun naa, ṣugbọn awọn ọlọpaa ni awọn ko fẹ eyi ti wọn tun lawọn yoo ṣe lọjọ Satide to kọja, nitori kinni naa ko ṣeeyan ni anfaani, jagidijagan ni wọn fi n da silẹ.
Bawọn ajijagbara naa ṣe lawọn ko gba ọrọ ọlọpaa wọle lo fa wahala laarin wọn.