Iru ki waa leleyii, ọkada meji fori sọ tirela l’Abẹokuta, lo ba tẹ wọn pa

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ni nnkan bii aago mẹjọ kọja iṣẹju mẹẹẹdọgbọn alẹ ọjọ Ẹti, ọgbọnjọ, oṣu kẹrin, ni awọn ọlọkada meji kan ku iku ojiji lagbegbe Kotopo, l’Abẹokuta. Niṣe ni wọn fori sọ tirela to n bọ jẹẹjẹ lodikeji ọna, ẹsẹkẹsẹ naa ni wọn dagbere faye.

Ohun ti Alukoro TRACE, Babatunde Akinbiyi, ṣalaye nipa iṣẹlẹ naa ni pe awọn ọkada meji yii lo n sare, ti wọn n wa iwakuwa to jẹ ki ijamba ṣẹlẹ.

O ni ladojukọ ileepo Forte Oil, to wa ni Kotopo, loju ọna Abẹokuta s’Ibadan, lawọn ọlọkada meji naa ti pade iku ojiji yii.

Akinbiyi ṣalaye pe Bajaj lawọn ọkada mejeeji, ọkan ni nọmba SGM 006 VG, ikeji ko ni rara. Nọmba tirela to tẹ wọn pa si ni AAB 969XV.

‘‘Iwakuwa ati aile ni suuru awọn ọlọkada yẹn lo fa asidẹnti yii, awọn ni wọn lọọ fori sọ tirela to n bọ lodikeji ọna jẹẹjẹ. A ti gbe ọkada mejeeji lọ si teṣan ọlọpaa Arẹgbẹ,  l’Abẹokuta, kan naa.’’ Bẹẹ ni Akinbiyi wi.

O tẹsiwaju pe oku ọkan ninu awọn ọlọkada naa ti wa ni mọṣuari, n’Idi-Aba, ẹbi ọkan yooku si ti gbe e lọ lati sin in.

 

Leave a Reply