Olori Ijo Ansarudeen, Shehu Ahmad, yoo ba gbogbo Musulumi aye sọrọ loni-in o

Nitori bi nnkan ṣe n lọ ni Naijiria wa loni-in yii, ati nitori asiko ti a wa yii, Olori ijọ Ansarudeen jakejado, Shehu AbdulRahman Ahmad, yoo ba gbogbo awon musulumi aye sọrọ loni-in yii, lati ṣalaye awọn ohun to ruju, ati awọn ohun ti ko yeeyan nipa ẹsin Islam ati awọn ohun to n lọ nigboro.

Ko si ani-ani pe ilu ko fara rọ lasiko yii, ibi gbogbo ni Naijiria lo n gbona, ogun awọn janduku Fulani ti wọn n pe ara wọn ni musulumi ati awọn alakatakiti mi-in ti wọn ko tun orukọ ẹsin Islaam ṣe. Ṣugbọn ṣe awọn eeyan yii lo n ṣe ohun to wu wọn ni, abi ilana kan wa to faaye gba wọn ninu Islaam? Kin ni ojuṣe musulumi ati ajọṣe wo lo yẹ ko wa laarin wọn ati awọn ti wọn ba jọ n gbe nibi kan? Kin ni musulumi gbọdọ ṣe lasiko aawẹ yii? Awọn ohun ti yoo jade ninu ọrọ ti Imam Ahmad yoo ba gbogbo aye sọ loni-in niyi.

Odu ni Lemọmu agba yii, ki i ṣe aimọ fun oloko, kari aye ni wọn ti mọ ọn bii onimimọ to kọyọyọ. Idi naa si niyi ti awọn ti wọn n ṣeto Ifọrọwanilẹnuwo Toyin Falọla (Toyin Falọla Interviews) ni Amẹrika fi wa Baba Aafaa nla naa kan, pe nibi ti ọrọ de yii, oun naa lo le ṣalaye ohun gbogbo faraalu ko ye wọn. Lati aago marun-un irọlẹ oni yii, ọjọ keji oṣu karun-un 2021, ni ifọrọwanilẹnuwo naa yoo ti bẹrẹ, nibi ti Shehu Ahmad yoo ti maa dahun ibeere gbogbo.

Ko si ibi ti ẹ ko ti le wo ijiroro nla yii lori ẹrọ ayelujara, bo jẹ lori You Tube, bo si jẹ lori Face Book tabi Instagram ti Alaroye Tv tabi ti Iwe Iroyin Alaroye, bo si jẹ ti Tunde Kelani ni Mainframe ni. Gbogbo musulumi pata, ati awọn ti ki i se musulumi paapaa, ni wọn yoo ni anfaani lati mọ ohun to n lọ. Ẹ pade Shehu Ahmad laago mariun-un oni o.

Leave a Reply