Ọkan lara awọn ẹgbọn Oloogbe Yinka Odumakin, Pasitọ Jacob Odumakin, ti sọ pe asọtẹlẹ ti wa tẹlẹ lori iku to wọle wẹrẹ mu akikanju ọkunrin naa lọ lọjọ Abamẹta, o ni awọn si gbadura si i, ṣugbọn bo ṣe ṣẹlẹ ye Ọlọrun.
Ninu ifọrọwerọ rẹ to ṣe pẹlu akọroyin ALAROYE nile awọn obi olóògbé naa to wa nìyi Mooro, nipinlẹ Ọṣun, o ṣalaye pe “Emi ni ẹgbọn Yinka, awa mẹrin ni baba bi, ṣugbọn ẹgbọn wa kan ti ṣalaisi, Isaac Odumakin, o waa ku awa mẹta, ninu awa mẹta yẹn, Yinka ni abikẹyin, oun naa lo tun ti lọ bayii.
“Nigba to wa ni General Hospital ni Eko, ninu oṣu keji, ọdun yii, mo duro ti i fun ọjọ mẹta nigba yẹn, nigba ti ara rẹ ya ni mo too kuro nibẹ.
“Ko too di pe iyawo rẹ pe mi ni mo ti ri i pe nnkan kan fẹẹ ṣẹlẹ, a si lọ sori-oke Baba Abiye, a tun lọ si Arakeji, a bẹrẹ si i gbadura, a tun ko awọn afadurajagun jọ, pe ki Ọlọrun ba wa lọra ẹmi rẹ. Ohun ti wọn sọ nigba naa ni pe igi tutu fẹẹ wo ṣaaju igi gbigbẹ, ohun to tumọ si naa ni pe Yinka fẹẹ ṣaaju baba rẹ, baba-ijọ lọ, ọmọ ọdun marundinlọgọfa si ni baba.
”A gbadura titi, a tun ba Ọlọrun jẹjẹẹ pe ki Ọlọrun ṣaanu Baba-Ijọ CAC Waasinmi, Moro, ko ba wa da ẹmi Yinka pada, ko fi aanu gba a pada, ṣugbọn ohun ti ko ye eniyan, o ye Ọlọrun”
Nigba ti Alaroye beere pe boya wahala ijangbara fun iran Yoruba ti oloogbe n ba kaakiri le wa lara awọn nnkan to yọri si iku rẹ yii, Pasitọ Jacob sọ pe gbogbo nnkan to ṣẹlẹ han si Ọlọrun.
Gẹgẹ bo ṣe wi, “Gbogbo rẹ naa lo so mọ ara wọn tori Yinka jẹ ẹni ti ko bẹru ẹnikẹni, o maa n fẹẹ sọ otitọ yẹn lai fẹẹ mọ ẹni to maa ba wi, igba mi-in gan-an to ba n sọ otitọ yẹn, mo maa n pe awọn bii Comrade Bayọ l’Ekoo pe ki wọn ba mi ba a sọrọ, pe ọrọ to n sọ ti pọ ju, wọn aa ni ki n fi i silẹ, pe nnkan to mọ niyẹn, awa naa si n jagun ẹmi fun un, ṣugbọn ohun gbogbo ye Ọlọrun”
Nipa isinku Oloogbe Yinka, ẹgbọn rẹ sọ pe, “Awọn Afẹnifẹre ti waa ki baba, wọn tun lọ si aafin Olumoro, bẹẹ gẹgẹ ni wọn ṣe lọ sile rẹ l’Ekoo lana-an (ọjọ Satide) lati lọọ ki Dokita Joe. Comrade Bayọ Lawal ti pe mi laipẹ yii pe awọn Afẹnifẹre lawọn làwọn maa sin Yinka, wọn ni awọn maa ṣepade lọsẹ yii, ati pe lẹyin ipade awọn lawọn maa pe mi bi gbogbo eto ba ṣe maa ri.”
O fi kun ọrọ rẹ pe awọn ko le sọ nipa iku Oloogbe Yinka fun baba ati iya rẹ latanat toti ṣẹlẹ nitori pe wọn ti di ogbo, wọn ni lati pe awọn iranṣẹ Ọlọrun atawọn agbaagba jọ, ki wahala mi-in ma baa tun ṣẹlẹ nibẹ.