Adewale Adeoye
Lati dẹkun ahesọ kan ti awọn eeyan n gbe kiri nipa ọmọkunrin to ti fẹrẹ sọ ara rẹ di obinrin tan nni, Idris Okunnẹyẹ ti gbogbo eeyan mọ si Bobrisky to n ṣewọn oṣu mẹfa lọwọ, awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn orileede Naijiria, ẹka tipinlẹ Eko, ‘The Lagos State Command Of The Nigerian Correctional Services’ (NCoS), ti lawọn ko fi ọmọkunrin naa sinu yara akanṣẹ tabi yara awọn eeyan pataki ninu ọgba ẹwọn Kirikiri to wa niluu Eko rara. Wọn ni inu iyara tawọn ẹlẹwọn bii tiẹ wa lawọn fi Bobrisky si, nitori pe aparo kan ko ga ju ọkan lọ lawọn fọrọ rẹ ṣe.
Aipẹ yii ni iroyin kan gba igboro kan pe iyara ọtọ ni awọn ẹṣọ inu ọgba ẹwọn Kirikiri fi Bobrisky si, to si jẹ yara ti awọn ọlọla maa n lọ, ti wọn si ni niṣe ni ọmọkunrin naa n gbadun bii eera inu ṣuga. Ṣugbọn awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn Kirikiri ti sọ pe ko soootọ ninu iroyin ẹlẹjẹ naa rara.
Alukoro ọgba ẹwọn naa, Ọgbẹni Rotimi Ọladokun, to sọrọ ọhun di mimọ laipẹ yii fawọn oniroyin sọ pe ko saaye kan lọ rẹpẹtẹ fawọn lati maa ṣetọju ẹlẹwọn kan bii ọba tabi ẹni pataki, o ni ibi ko ju ibi, ba a ṣe bi ẹru, bẹẹ la bi ọmọ. O ni ẹsun iwa ọdaran to gbe Bobrisky wa sinu ọgba ẹwọn ọhun naa lo gbe awọn yooku rẹ wa, ko yẹ kawọn ya a sọtọ tabi ṣe itọju rẹ yatọ sawọn yooku.
Atẹjade kan ti wọn fi sita lori iṣẹlẹ ọhun sọ pe ‘‘O ti de etiigbọ awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn Kirikiri, niluu Eko, pe awọn kan n gbe iroyin kaakiri pe, inu yara ọtọ to dun un wo loju daadaa la fi Bobrisky to n sẹwọn lọdọ wa si, ko sootọ kankan ninu iroyin naa rara, o yẹ ka pe awọn to gbe iroyin ọhun sori ẹrọ ayelujara lẹjọ ni, ṣugbọn a ko fẹẹ pẹlu ọbọ jawura lori ọrọ naa la ṣe dakẹ jẹẹ.
‘‘Ofin faaye gba awọn ẹlẹwọn pe ki awọn ẹbi wọn tabi lọọya wọn waa sabẹwo si wọn lọsọọsẹ, anfaani ọhun ṣi wa fun Bobrisky bakan naa, oun naa lore-ọfẹ lati ri awọn ẹbi rẹ tabi lọọya rẹ lẹẹkan laarin ọsẹ. Fun idi eyi, a n rọ awọn araalu gbogbo pe ki wọn ma ṣe gba iroyin naa gbọ rara, ko sootọ nibẹ’’.
Ẹwọn oṣu mẹfa ni adajọ ile-ẹjọ kan niluu Eko sọ Bobrisky si. Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣẹ owo ilu mọkumọku ‘Economics And Financial Crime Commission’ (EFCC), lo foju Bobrisky bale-ẹjọ. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o ṣe owo Naira ile wa baṣubaṣu nita gbangba, iwa ti wọn ni ki i ṣohun to daa, ti ijiya nla si wa fẹni to ba ṣe bẹẹ lawujọ wa.