Bi awọn ọmọ Naijiria ṣe n pariwo, ti wọn n ṣe iwọde kiri loriṣiiriiṣi lati fẹhonu wọn han, Aarẹ Muhammed Buhari ti sọ pe awọn ko ni i fagi le ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n gbogun ti idigunjale ati iwa ọdaran, SARS, gẹgẹ bi awọn kan ṣe fẹ, atunto ni yoo ba ẹka ileeṣẹ agbofinronaa.
Ninu ọrọ ẹ lori ikanni abẹyẹfo (twitter) lo ti sọ pe, “Emi ati ọga ọlọpaa patapata ti ṣepade, ohun ti a si jọ fẹnu ko le lori ni pe a oo ṣatunṣe sọrọ awọn ọlọpaa SARS. Gbogbo ohun to n ṣẹlẹ pata, paapaa awọn iwa itiniloju tawọn ẹṣọ agbofinro hu, ni a n gbọ gbogbo bo ṣe n Iọ, bẹẹ ni mo fẹẹ fi da yin loju pe ọrẹ araalu ni ọlọpaa gbọdọ jẹ, wọn si ni lati mojuto araalu daadaa.”
Aarẹ Buhari tun fi kun un pe oun ti paṣẹ fun ọga ọlọpaa lati wa gbogbo awọn to n huwa ti ko bojumu jade ninu iṣẹ ọlọpaa, ki wọn si foju winna ofin gẹgẹ bo ti yẹ
‘Mo fẹ ki awọn eeyan orilẹ-ede yii ni suuru, gbogbo ohun ti wọn n beere fun la oo gbe igbesẹ lori ẹ gẹgẹ bi wọn ti ṣe lẹtọọ lati fẹhonu wọn han lori ohun ti wọn ko ba fẹ.’ Buhari lo sọ bẹẹ.
O ni ohun toun mọ daju ni pe ojulowo ẹṣọ agbofinro lọkunrin ati lobinrin ni Naijiria ni, bẹẹ ni wọn ki i fiṣẹ wọn ṣere lori eto abo, ati pe ijọba yoo tubọ maa kun wọn lọwọ daadaa.
Tẹ o ba gbagbe, lati nnkan bii ọjọ meloo kan sẹyin ni iwọde ti n waye kaakiri orilẹ-ede yii, ninu ẹ naa lẹmi araalu ti bọ, ti ọlọpaa paapaa naa ku, nigba ti awọn eeyan n sọ pe dandan ni ki ijọba ko awọn ẹṣọ SARS kuro nilẹ patapata.