A ko ni i gba oṣiṣẹ ti ko ba gba abẹrẹ Korona laarin ọsẹ meji laaye lẹnu iṣẹ l’Ondo-Afọlabi

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ijọba ipinlẹ Ondo ti fun awọn oṣiṣẹ rẹ ni gbedeke ọsẹ meji pere lati fi gba abẹrẹ ajẹṣara ajakalẹ arun Korona to n lọ lọwọ.

Aṣẹ yii waye ninu atẹjade kan ti Ọgbẹni Afọlabi to jẹ akọwe agba lọfiisi olori awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Ondo fi sita lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.

O ni igbesẹ ọhun waye latari bi arun Korona ṣe n fi ojoojumọ tan kalẹ si i kaakiri orilẹ-ede yii.

Eyikeyii ninu awọn oṣiṣẹ ti ko ba ti ni kaadi to ṣafihan pe oun ti gba abẹrẹ ajẹṣara naa lo ni wọn ko ni i fun laaye lati maa wọ ile tabi ọfiisi ijọba ni kete ti gbedeke ọsẹ meji naa ba ti pari.

Bakan naa lo tun rọ awọn araalu lati ri i daju pe wọn n pa gbogbo ofin ati ilana to de itankalẹ arun naa mọ ki akitiyan ijọba le seso rere.

Kọmisanna feto iroyin nipinlẹ Ondo, Donald Ọjọgo, ti kọkọ sọ fawọn eeyan ninu ipade awọn oniroyin kan to pe l’Ọjọruu, Wẹsidee, pe gbigba abẹrẹ ajẹṣara Korona ti pọn dandan fun gbogbo olugbe ipinlẹ Ondo.

Ẹni to ba ti kuna lati gba abẹrẹ ọhun, ko si mu kaadi rẹ lọwọ, lo ni ko ni i lanfaani ati maa wọle lọọ ba wọn jọsin mọ lawọn ṣọọsi ati mọṣalaasi gbogbo to wa nipinlẹ naa.

 

Leave a Reply