A ko sanwo fawọn agbebọn ta a fi ri awọn akẹkọọ ti wọn ji ko gba pada- Gomina Zamfara

Faith Adebọla

Gomina ipinlẹ Zamfara, Bello Matawalle,  ti kede pe awọn ti ri awọn akẹkọọ-binrin tawọn agbẹbọn lọọ ji gbe ninu ọgba ileewe ijọba Government Girls Secondary School, to wa ni Jangebe gba, wọn lawọn agbebọn naa ti yọnda wọn lafẹmọju ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii. Iyawo gomina ọhun, Hajia Aisha Bello Matawalle, lo ṣaaju ikọ ijọba to lọọ tẹwọ gba awọn ọmọ naa, wọn si ti ko wọn lọ sọfiisi gomina.

Amọ ṣa, ọrinlerugba o din ẹyọ kan (279) lawọn ọmọ tawọn agbebọn naa tu silẹ ni nnkan bii aago mẹrin idaji yii, bẹẹ ọọdunrun ati mẹtadinlogun nijọba sọ pe awọn janduku naa ko sahaamọ wọn nigba ti wọn ji wọn gbe lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keji, ọdun yii.

A gbọ pe meje ninu awọn ọmọ naa raaye sa mọ awọn agbebọn naa lọwọ, ti wọn si fẹsẹ rin pada wọlu lọjọ keji iṣẹlẹ ọhun.

Ni bayii, awọn ọmọ mọkandinlọgbọn lo ṣi wa lahaamọ awọn apamọlẹkun ẹda yii, ti wọn o ti i tu silẹ.

Gomina Matawalle, nigba to n sọrọ nipa iṣẹlẹ yii lori ikanni ayelujara rẹ,  kọ ọ sibẹ pe: “Alhamdulillah! Inu mi dun lati kede pe wọn ti yọnda awọn ọmọleewe GGSS, Jangebe, ti wọn ji gbe lọjọsi o, wọn ti kuro lahaamọ awọn to ji wọn gbe. A dupẹ pe a bori gbogbo idena ti wọn fẹẹ fun wa lati ri awọn ọmọ naa gba pada. Mo fẹ kẹyin ọmọ Naijiria elero rere ba wa yọ pe awọn ọmọbinrin wa ti wa lalaafia bayii, ko sewu fun wọn.

Matawalle lawọn ti ṣeto bawọn ọmọ itọju iṣegun to peye lọkọọkan. O tun sọ pe awọn o sanwo fawọn agbebọn naa ki wọn too fawọn ọmọ naa lominira, niṣe lawọn kan jọọ lajọsọ ọrọ.

Leave a Reply