A maa fi Ṣọun Ogbomọṣọ tuntun jẹ laipẹ- Makinde

Ọlawale Ajao Ibadan

Bi ileri ti Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ṣe fawọn araalu Ogbomọṣọ ba ti isalẹ ọkan ẹ jade, a jẹ pe awọn araalu naa ko ni i pẹẹ lọba tuntun.

Nigba to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lẹkun Ogbomọṣọ sọrọ nirọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni gomina fi awọn araalu naa lọkan balẹ pe ara oun ti wa lọna lati gbe ọpa aṣẹ le ọba wọn tuntun lọwọ laipẹ rara, iyẹn bi awọn afọbajẹ ilu naa ba ṣe ojuṣe wọn ni ibamu pẹlu ilana to tọ.

Makinde ṣalaye pe loootọ niwe to ni i ṣe pẹlu ọrọ fifi ọba tuntun jẹ niluu Ogbomọṣọ ti wa lori tabili lọfiisi oun, ṣugbọn ẹjọ to wa ni kootu lori ọrọ naa lo n dena igbesẹ lati kede Ṣọun tuntun.

Gẹgẹ bo Se sọ, “Ki i ṣe pe awa naa fẹ ko pẹ to bayii ka too jẹ ọba tuntun niluu Ogbomọṣọ, ṣugbọn awọn kan ti gbe ọrọ oye jijẹ yii lọ si kootu, wọn ni wọn ko fun awọn lanfaani lati dupo ọba yii, mo si ti rọ gbogbo awọn ti ọrọ yii kan lati yanju ọrọ naa nitubi-inubi, ka le raaye tẹsiwaju ninu awọn igbesẹ to ba yẹ ka gbe lati yan ọba tuntun.

“Oju temi paapaa ti wa lọna lati ri Ṣọun tuntun, ṣugbọn ohun to jẹ mi logun ni pe ki awọn awọn afọbajẹ ṣe gbogbo ohun ti wọn ba maa ṣe ni ibamu pẹlu ofin ati ilana to tọ. Bi ẹjọ ba kuro ni kootu, ti awọn afọbajẹ si ṣe ojuṣe wọn bo ṣe yẹ, kiakia la maa fọwọ si ẹnikẹni ti wọn ba yan gẹgẹ bii Ṣọun Ogbomọṣọ tuntun.

Ta o ba gbagbe, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila, ọdun 2021, eyi to ku ọjọ bii mẹwaa ti yoo fi pe ọdun kan bayii, ni Ṣọun Ogbomọṣọ, Ọba Jimọh Oyewumi Ajagungbade Kẹta waja, to dara pọ mọ awọn baba nla ẹ lẹyin to fi ọdun mejidinlaaadọta (48) gunwa sori itẹ ọla naa.

Leave a Reply