A maa fofin de aṣọ okirika, o lewu fun ilera araalu-Ileeṣẹ Aṣọbode

Adewale Adeoye

Fun awọn kọọkan ti wọn ko mọ tẹlẹ pe ki i ṣohun to da rara lati maa ko aṣọ okirika, iyẹn awọn aṣọ aloku wọlu wa lati ilẹ okeere.

Awọn aṣọbode orileede wa, Kọsitọọmu, ti sọ pe awon yoo maa fọwọ ofin mu gbogbo awọn oniṣowo yoowu ti wọn ba fẹẹ ko aṣọ aloku ti wọn tun maa n pe ni okirika wọ orileede wa bayii.

Ọkan lara awọn ọga ajọ naa to sọrọ yii di mimọ fawọn oniroyin laipẹ yii lo sọ pe ewu nla to pọ lo wa ninu bi awọn oniṣowo kan ṣe n ko awọn aṣọ naa wọlu wa bayii. O ni ko yẹ rara ki awọn alaṣẹ ijọba orileede yii faaye gba a rara, nitori ohun itiju nla gbaa lo jẹ fun orileede olominira bii tiwa yii ba a ṣe n faaye gba awọn kan pe ki wọn maa ko aṣọ okirika wa silẹ wa.

O ni ko sẹni kan to mọ ibi tabi ẹni gan-an to lo awọn aṣọ naa ku ko too di pe awọn oniṣowo ọhun loọ ko wọn wa sorileede wa fun lilo awọn araalu.

Ọga agba naa sọ pe bii pe wọn ko bọwọ rara fun awọn alaṣẹ ijọba ile wa ati awọn ọmọ orileede wa ni wọn ṣe n ko awọn aṣọ okirika naa wọlu wa bayii.

‘Orileede wa Naijiria ki i ṣe ori aatan teeyan kan le maa waa da awọn aṣọ okirika sibẹ mọ rara, ojulowo aṣọ lo yẹ ka maa lo nigba gbogbo.

Ọlọrun ti kẹ wa ju pe ki awọn kan maa waa lọ soke okun, ki wọn si maa ko aṣọ okirika wa fawọn ara orileede wa bayii.

‘Ọwọ ofin la maa fi mu gbogbo awọn to ba tapa sofin ijọba lori aṣọ okirika naa bayii, nitori ewu nla gbaa lo wa fun awọn araalu bi wọn ṣe n wọ aṣọ okirika naa nigba gbogbo.

‘Wọn kan n gbe e wa silẹ wa ni, ta a si n wọ ọ bo ti ṣe wu wa lai bikita ohun to le ṣẹlẹ sawa naa paapaa.

Leave a Reply