Faith Adebọla, Eko
CP Hakeem Odumosu, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, ti sọrọ nipa bawọn eeyan kan ṣe n pariwo pe gbogbo ohun to ba gba lawọn maa fun un, awọn maa ya kuro lara Naijiria, awọn maa da Orileede Oodua ati Orileede Biafra silẹ, o ni toju tiyẹ laparo ileeṣẹ ọlọpa fi n ṣọ awọn eeyan ọhun.
Odumosu ni ko sohun to buru feeyan lati sọ ifẹ ọkan rẹ, ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ko ni i kawọ gbera maa woran pẹlu bawọn ẹgbẹ kan ti wọn leri iyapa ọhun ṣe sọ pe to ba pe fun kawọn da omi alaafia ilu ru, awọn yoo ṣe bẹẹ.
Nibi ipade akanṣe kan ti Gomina Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Eko pe lori eto aabo ipinlẹ ọhun, eyi ti wọn ṣe laaarọ ọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii ni Alausa, Ikẹja, ni Odumosu ti sọrọ naa.
Kọmiṣanna ọhun ni, iwadii tawọn ṣe ti fihan pe nnkan bii ẹlẹgbẹjẹgbẹ mẹrinlelogun lawọn ti sami si kaakiri ipinlẹ ọhun ti wọn n ṣagbatẹru yiya kuro lara Naijiria, awọn si n ṣọ wọn loju mejeeji ni.
“Ileeṣẹ ọlọpaa Eko ti gbọ nipa awọn ẹgbẹ kan ti wọn n leri lati da wahala silẹ niluu Eko latari erongba wọn pe ki ẹya kan tabi agbegbe kan ya kuro lara Naijiria. A ti n ṣọ wọn lọwọ lẹsẹ, gbogbo igbesẹ wọn la n ṣọ pẹkipẹki, a o si ni i faaye gba igbokegbodo idaluru eyikeyii.
“A rọ awọn araalu lati tete ta awọn agbofinro lolobo gbara ti wọn ba ti ri nnkan ajeji tabi awọn eeyan ti irin wọn mu ifura dani layiika wọn, ẹ jẹ ka pinnu pe gbogbo ohun ta a ba ri la maa sọ.”
Apero naa, eyi ti gomina ipinlẹ Eko, igbakeji rẹ, awọn lọgaa lọgaa nileeṣẹ ologun, awọn ẹṣọ alaabo aladaani ati tijọba, atawọn araalu kan, pesẹ si, dabaa, wọn si fẹnu ko pe kijọba bẹrẹ si i gbẹsẹ le awọn ile pako, ile akọku, awoku, otẹẹli, ile aṣẹwo atawọn ọkọ ti wọn ti pa ti tawọn janduku, ẹlẹgbẹ okunkun atawọn adigunjale fi n ṣe ibuba wọn l’Ekoo, ki wọn si ba awọn to ni irufẹ ile bẹẹ ṣẹjọ.
Wọn ni kijọba bẹrẹ si i wọ awọn mọto to ti bajẹ, tabi ti wọn pa ti kuro lawọn adugbo tawọn eeyan n gbe nipinlẹ Eko.