Iwa oju dudu ni ki Fulani maa da maaluu kaakiri igboro, opin gbọdọ de ba a-Oluwoo  

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

 Bi gbogbo nnkan ba lọ bi wọn ṣe ṣeto rẹ, ọjọ kejidinlogun, oṣu yii, ni ipade pataki kan yoo waye laafin Oluwo ilẹ Iwo, Ọna AbdulRasheed Adewale Akanbi. Ohun ti ipade naa da le lori ni lati wa alaafia laarin awọn agbẹ to wa niluu Iwo ati awọn darandaran.

Nigba ti kabiyesi n ba ALAROYE sọrọ lori foonu lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ọba alaye naa ṣalaye pe oun ti ranṣe si awọn agbẹ jake-jado ilu Iwo, bẹẹ loun ti ranṣẹ si awọn Fulani to wa nibẹ paapaa, awọn mejeeji yoo si jọ jokoo apero laafin oun, nibi ti ajọsọ ọrọ yoo ti waye lori bi awọn darandaran naa yoo ti maa ṣiṣe wọn ti ko fi ni i si gbọnmi-si-i omi-o-to-o laarin awọn mejeeji.

Kabiyesi ni pẹlu bi ohun gbogbo ti polukurumusu lasiko yii, ti gbogbo ilu si n pariwo, o ni ọna abayọ si iṣoro awọn agbẹ ati awọn Fulani lo yẹ ka wa, ki i ṣe ka maa pariwo pe ki a le awọn eeyan naa danu.

Ọba Oluwoo ni awọn Fulani to ti wa laarin wa tipẹ yii ki i ṣe ọdaran, o ni wọn ti wa niluu Iwo lati aye awọn baba nla awọn ni, ti wọn si n gbe igbesi aye wọn, ti ko si si wahala kankan. O ni agboole kan wa ti wọn n pe ni ile Hausa titi doni niluu Iwo, nitori awọn eeyan naa lo n gbebẹ nigba naa. O fi kun un pe awọn baba nla awọn lo gba awọn Fulani yii lalejo nigba naa, nitori awọn ni wọn n kọ wọn ni keu, ko si si wahala kankan pẹlu wọn nigba ti a n sọ yii.

 

Ọba Akanbi ni awọn ti wọn n jiiyan gbe, ti wọn n da wahala si ilu, ki i ṣe awọn Fulani ta a n ri ni agbegbe wa yii, o ni ọpọ awọn to n ṣiṣẹ buruku naa lo jẹ ọmọ ogun Gadaffi to ti figba kan jẹ olori ilẹ Lybya, nitori oun lo maa n ko awọn eeyan naa jọ kaakiri ilu ati orileede, to maa n lo wọn fun ogun, ṣugbọn nigba ti ọkunrin naa ku tan lawọn eeyan naa fọn kaakiri ilẹ Afrika pẹlu awọn ohun eelo ija oloro buruku lọwọ wọ, awọn ni wọn si n da araalu laamu.

Oluwoo ni akoba nla ni awọn eeyan naa n ṣe fun awọn Fulani to jẹ ojulowo ti wọn ki i si i ṣe onijagidijagan nitori niṣe ni wọn maa n dunkooko mọ awọn naa, ti wọn si maa n kọju ija si wọn.

Kabiyesi ni gbogbo wa ko le sun ka kọri sibi kan naa lori ọrọ awọn Fulani to n paayan, ti wọn si n fi maaluu jẹ oko awọn agbẹ yii. Eyi lo mu ki oun ṣeto ipade pataki kan laarin awọn agbẹ ilu naa.

O ni igbesẹ ti awọn fẹẹ gbe ni pe awọn yoo ṣeto idanilẹkọọ fawọn Fulani naa. Bo ba jẹ pe ọgọrun-un ni gbogbo wọn, eto ti awọn yoo ṣe ni pe aadọta ninu wọn yoo wa ni gaa, ti wọn yoo duro ti maaluu wọn, awọn aadọta yooku yoo jade lati wa koriko ti awọn eeyan naa yoo jẹ.

O ni aye ti laju ju ki awọn Fulani maa ko maaluu kaakiri ilu, ki wọn ni awọn fi n jẹko, Oluwoo ni aṣa oju dudu ti ko bojumu rara ni, o si yẹ ki opin de ba eleyii.

O ni awọn yoo wo bi igbesẹ naa yoo ṣe ṣiṣẹ fun oṣu mẹta akọkọ, awọn yoo si ṣe ayipada to ba tun yẹ lẹyin eleyii.

Ọba Akanbi ni pẹlu igbesẹ yii, ko ni i si Fulani to gbọdọ maa da maaluu kiri tabi ko fi jẹ oko oloko. O ni ẹni ti awọn ba ti gba mu, awọn maa gbẹsẹ le awọn maaluu rẹ, awọn aa si ko o lọ si tọlọpaa, lẹyin naa lawọn maa ko o wa si aafin. Bi iru ẹni bẹẹ ko ba si sanwo itanran, ko ni i ko maaluu naa kuro.

Bakan naa lo sọ pe ofin ti wa niluu Iwo, Fulani to ba fi maaluu jẹ oko gbọdọ sanwo ohun ti ẹran rẹ ba jẹ fun awọn agbẹ, wọn si n ṣe bẹẹ bi oun ti n sọrọ yii. O ni ipade ti yoo waye lọjọ kejidinlogun yii yoo fun awọn Fulani to ti wa niluu tele ati agbẹ lanfaani lati le maa gbe pọ lai si wahala kankan.

Leave a Reply