Monisọla Saka
Aarẹ Bọla Tinubu, ti ṣeleri lati ṣagbeyẹwo owo oṣiṣẹ to kere ju, nitori lara ileri toun ṣe ni lati mu igbe aye rọrun fawọn ọmọ Naijiria.
O ni igbaye-gbadun awọn ọmọ Naijiria jẹ ijọba oun logun, bẹẹ loun n wa gbogbo ọna lati mu amugbooro ba eto ọrọ aje.
Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni Aarẹ sọrọ yii lasiko tawọn gomina ẹgbẹ oṣelu APC, Progressive Governors Forum (PGF), ti gomina ipinlẹ Imo, Hope Uzodinma, jẹ alaga fun ba a lalejo nileejọba l’Abuja.
O nijọba apapọ atawọn to wa labẹ ẹ ni lati ṣiṣẹ papọ lori ọrọ naa.
Tinubu ni, “A ni lati ṣe awọn iṣẹ ọpọlọ ati wiwa awọn eeyan ti wọn to gbangbaa sun lọyẹ lori ọrọ owo-oṣu oṣiṣẹ to kere ju. Ọrọ ṣunnukun ni, gbogbo wa la maa ni lati dijọ wo o, ati owo to n wọle naa. A gbọdọ ṣiṣẹ takuntakun lati ro ọna towo n gba wọle fun wa lagbara, ati ọna ti a oo maa gba na an.
Ipade yii ko ṣajoji si mi, ọrọ pataki si lohun ta a tori ẹ jokoo, ta a n jiroro le lori. Ọrọ nipa Naijiria si leleyii, ki i ṣe nipa Bọla Tinubu”.
O waa rọ awọn gomina naa lati lo anfaani bawọn araalu ṣe dibo yan wọn laarin ogunlọgọ eeyan ipinlẹ wọn lati ṣiṣẹ ọtun ati ayipada nla laye awọn eeyan. O fi da wọn loju pe oun gẹgẹ bii ẹni kan yoo ṣiṣẹ ti yoo ṣanfaani fawọn ọmọ Naijiria.
Nigba to n sọrọ lori gbese to de ba, o ni, “O yẹ ka ṣayẹwo si ọrọ ipaarọ owo pẹlu tilẹ mi-in.
Owo rọgunrọgun ni gbese ti mo jogun lọdọ awọn ti wọn ṣejọba ṣaaju mi. Gbogbo ẹyin onitẹsiwaju ati alarojinlẹ labẹ aburada ẹgbẹ oṣelu APC, ni ipa pataki lati ko ninu dida awọn eeyan wa lẹkọọ, ati lati ri i daju pe a wa ọna lati yanju ara wa bo ṣe yẹ”.
O ni lori eto ijọba toun yii, gbayawu ni ilẹkun oun ṣi silẹ lati tẹti sawọn eeyan, ati lati jọ jiroro lojuna ati le wa ọna abayọ si ọrọ eto aabo atawọn wahala mi-in to n kọju orilẹ-ede yii.