Faith Adebọla
Yoruba bọ, wọn ni iṣu atẹnumọrọ ki i jona, ohun to ba si n dun ni ni i pọ lọrọ ẹni. Owe yii lo wọ ọrọ tawọn agbaagba ẹya Igbo sọ nibi ipade wọn pe awọn o ni i tẹwọ gba ipo Igbakeji aarẹ ninu eto idibo gbogbogboo to n bọ lọdun 2023. Wọn ni ohunkohun to ba yatọ si ki ẹya Igbo bọ sipo aarẹ lọdun 2023, awọn ti ṣetan lati ya kuro lara Naijiria loju-ẹsẹ.
Ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni Igbo Elders Consultative Forum, eyi ti ọpọ awọn alẹnulọrọ nilẹ Ibo wa ninu rẹ, lo sọ eyi di mimọ nibi ipade kan ti wọn se l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu keji yii, niluu Abuja.
Lara awọn to pesẹ sipade naa ni gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ ri, Oloye Chukwuemeka Ezeife, minisita feto ẹkọ tẹlẹ, Ọjọgbọn Solomon C. Madubuike, Akọwe agba fun ẹgbẹ Ohaneze Ndigbo l’Abuja, Ọmọwe Nkonye Kingsley, Ọba ilẹ Awka, nipinlẹ Anambra, Alayeluwa Igwe Ibe Nwosu, Akọwe ẹgbẹ IECF naa, Dokita Charles Nwekeaku, atawọn eekan eekan ilẹ Ibo mi-in.
Chukwuemeka Ezeife, ti i ṣe alaga ẹgbẹ naa sọ lẹyin ipade ọhun pe: “Pẹlu bi ọpọ eeyan ṣe n sọ pe asiko ti to lati yi ipo aarẹ lọ sagbegbe Guusu orileede yii lọdun 2023, a rọ ẹyin ojulowo ọmọ ẹya Igbo to dantọ, to ni ala rere lọkan, to lakinkanju, to ṣee gbara le, to si lawọn iwa amuyẹ fun ipo aarẹ lati jade, ki wọn sọ erongba wọn di mimọ, ki wọn si fi tagbara tagbara ṣiṣẹ lati de ipo naa.
“A o fi ọrọ yii ṣe ṣereṣere o, a o fẹ kawọn alainikan-an-ṣe ti yoo maa ṣe bii ọmọọdọ jade, a nifẹẹ si awọn to fẹẹ ṣe igbakeji aarẹ fun ẹya mi-in lọdọ wa, tori a o ni i fojuure wo ẹnikẹni ninu awọn ọmọ wa lọkunrin tabi lobinrin to ba gba lati ṣe igbakeji aarẹ fun aarẹ ti ki i ṣe ẹya Igbo lọdun 2023, a maa fiya gidi jẹ ẹnikẹni to ba ṣe’ru ẹ ni.
Ni gbogbo ọna, ni ti ẹtọ, ni ti ilana, ni ti idajọ ododo, ẹya Ibo lo kan lati fa aarẹ kalẹ lọdun 2023, tori gbogbo ẹya pataki yooku lo ti wa nipo aarẹ yikayika lorileede yii.
A ti n reti wọn, a n duro de awọn ẹgbẹ oṣelu wọnyi, wọn maa kan idin ninu iyọ lọtẹ yii ni, a maa kan wọn labuku gidi ni ti wọn ba tun lero pe awọn le rọ ẹya Ibo sẹyin, tabi ti wọn ro pe awọn maa lo anfaani tiwa mọ tiwọn. A o ni i gba rara, tori ẹya Igbo ni eeyan to to tan, to ṣee gbẹkẹ le, to si ni iriri ati laakaye gidi lati ṣe aarẹ Naijiria lọdun 2023.
Bi wọn o ba jẹ ka fa aarẹ kalẹ, ko sohun meji ju ka ya kuro lara Naijiria lọ, a o si ṣe bẹẹ loju-ẹsẹ ni.”