Faith Adebola, Eko
Owe awọn agba ni pe ‘ọwọ to ba dilẹ l’eṣu n wa iṣẹ fun’, eyi lo mu iyawo Gomina Babajide Sanwo-Olu ti ipinlẹ Eko, Abilekọ Ibijọkẹ Sanwo-Olu ṣekilọ pe ewu gidi ni bawọn akẹkọọ fasiti ko ṣe rikan-ṣekan lasiko yii, ti wọn o si ni yara ikawe wọn, tori iru ọwọ to dilẹ bẹẹ l’eṣu n ya lo lati huwa aidaa.
Sanwo-Olu sọrọ yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrin, oṣu Karun-un yii, nibi akanṣe apejẹ kan ti awọn lọgaa-lọgaa lẹnu iṣejọba ipinlẹ Eko fi sami opin aawẹ Ramadan tawọn ẹlẹsin Musulumi ṣẹṣẹ pari, ati ọdun itunu aawẹ. Ile ijọba to wa ni Alausa, Ikẹja, lẹgbẹẹ ọfiisi gomina Eko, layẹyẹ naa ti waye.
Obinrin akọkọ nipinlẹ Eko naa sọ pe:
“Awọn ọmọ wa gbọdọ pada sẹnu ẹkọ wọn. Bii ẹni n fi ina ṣere lẹgbẹẹ ẹtu ibọn lo jẹ, bawọn ọmọ wọnyi ṣe jokoo sile lai ṣe ohunkohun. Ọwọ to ba dilẹ l’eṣu n bẹ lọwẹ. Awọn ọmọ wa, awọn akẹkọọ fasiti, to jokoo sile fun oṣu meji gbako, ki i ṣe nnkan amuyangan fun wa rara, tori bẹẹ, gbogbo igba ti anfaani ẹ ba ṣi silẹ, awa obi, paapaa awa iya, gbọdọ kegbajare nipa ẹ.
“A mọ pe iyanṣẹlodi tawọn ẹgbẹ olukọ fasiti (ASUU) gun le lo fa a. A parọwa ni o, niṣe la n bẹbẹ pe k’Ọlọrun jẹ ka ri ọrọ yii yanju o. Inu mi o dun, ara mi o lelẹ, pe awọn ọmọ wọnyi kan jokoo sile, gbogbo nnkan to ba gba ni ka fun un kawọn ọmọọlọmọ yii le pada sẹnu ẹkọ iwe wọn.”
Bakan naa ni Ibijọkẹ Sanwo-Olu tun gba awọn akẹkọọ naa nimọran pe ki wọn ma ṣe lo asiko yii lati kẹgbẹkẹgbẹ tabi lọwọ ninu iwa palapala, iwa iṣekuṣe, iwa ipanle ati ibalopọ jatijati to kun igboro. O si tun rọ awọn obi lati ri i daju pe wọn mojuto awọn ọmọ wọn, titi ti ọrọ iyanṣẹlodi naa yoo fi yanju.
“Gẹgẹ bii obi, ẹ jẹ ka fi apẹẹrẹ rere lelẹ fawọn ọmọ wa, nipa mimojuto gbogbo nnkan ti wọn ba n ṣe, paapaa awọn ogo wẹẹrẹ wa. Ko buru ta a ba n da si awọn nnkan ti wọn n ṣe ni kọlọfin, ẹ ma jẹ ka fi wọn silẹ nigba kan, wọn le sọ pe a o jẹ kawọn rimu mi loootọ, ṣugbọn ojuṣe wa gẹgẹ bii obi la n ṣe yẹn, a fẹẹ tọ wọn sọna to daa ni, tori ọjọ-ọla wọn.
“O tun ṣe pataki ka di ọrẹ wọn, ki wọn le sọ tinu wọn jade fun wa, ki wọn si gbara le wa.”
Bakan naa lo gba awọn ẹlẹsin Musulumi lamọran lati ma ṣe yẹsẹ ninu awọn ẹkọ ti wọn jere lasiko aawẹ Ramadan, bii fifi aanu han sọmọlakeji, ṣiṣoore, fifi ifẹ han, bibọwọ funni, wiwa alaafia, ka si maa gbe nirẹpọ pẹlu ara wa.