Faith Adebọla, Eko
Ẹgbẹ Afẹnifẹre to n ja fun ominira Yoruba, ti sọ pe awọn o ni i lọọ ba Aarẹ Muhammadu Buhari sọrọ, bẹẹ lawọn o ni i rawọ ẹbẹ kankan si i pe ko lo agbara rẹ lati tu Oloye Sunday Adeyẹmọ tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho silẹ lahaamọ, tori ko si ẹsun kan lọrun ọkunrin naa, ko si si ẹjọ kankan to n jẹ lọwọ.
Akọwe ẹgbẹ Afẹnifẹre, Ọgbẹni Ṣọla Ebiseni, lo sọrọ yii lorukọ ẹgbẹ naa lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, o ni, “ko si idi kankan tawọn Yoruba yoo fi lọọ bẹ ijọba apapọ lati tu Sunday Igboho silẹ. Lai ka bi ijọba Buhari ṣe n huwa ta-ni-maa-mu-mi si, a o ni i fara mọ iṣakoso ti ko bofin mu eyikeyii, ilana ofin nikan la fara mọ ni Naijiria.
Ṣebi ile-ẹjọ ti paṣẹ pe bijọba ṣe ṣakọlu sile Sunday Igboho lọganjọ oru lọjọsi, ti wọn fẹẹ pa a, ṣugbọn to jẹ awọn ẹmẹwa ẹ meji ni wọn pa, ti wọn si ba ọpọ dukia olowo iyebiye jẹ ko bofin mu, wọn lawọn tẹrọriisi ni wọn maa n ṣeru ẹ, wọn si ni kijọba san biliọnu lọna ogun Naira fun un gẹgẹ bii ẹtọ ẹ lori awọn nnkan ti wọn bajẹ.
Ṣe ijọba ti san an? Awọn ti wọn lọọ ya bo ile naa ki i ṣe agbofinro rara, wọn kan wọṣọ ijọba lasan ni, afẹmiṣofo ni wọn, tẹrọriisi gidi ni wọn.
Ṣebi ile-ẹjọ ti paṣẹ pe Sunday Igboho ko jẹbi kankan, wọn lọkunrin naa ko lẹjọ i jẹ, ijọba ni wọn da lẹbi, ti wọn si bu owo ti wọn gbọdọ san fun wọn.”
Ẹgbẹ Afẹnifẹre ni awọn nigbagbọ pe ododo ni yoo leke lori ahamọ ti wọn sọ Sunday Igboho si.
Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni Oluwoo ti ilẹ Iwo, Ọba AbdulRasheed Akanbi, gba awọn agbaagba Yoruba nimọran lati wo awokọṣe bawọn agbaagba ilẹ Ibo ṣe lọọ ba Buhari sọrọ lati tu Nnamdi Kanu to wa lahaamọ awọn ẹṣọ ọtẹlẹmuyẹ DSS, l’Abuja silẹ, latari ẹjọ to n jẹ lọwọ, ti Aarẹ si loun yoo ronu lori ẹbẹ wọn.
Ṣugbọn ẹgbẹ Afẹnifẹre lawọn o ni i ṣeru ẹ ni tawọn, tori Sunday Igboho ko dẹṣẹ kan ti wọn le tori ẹ fi i satimọle lorileede Olominira Bẹnẹ.