Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Latari ọrọ-aje orilẹ-ede yii to n ṣojojo, ti ijọba apapọ atawọn ipinlẹ kan si ni awọn yoo ni lati din owo awọn oṣiṣẹ ijọba ku ni, Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ti loun ko ni i din owo-oṣu oṣiṣẹ ku ni toun. O ni iye owo to kere ju tijọba apapọ fọwọ si (Minimum wage) naa loun yoo maa san lọ.
Nibi eto iṣinu aawẹ Ramadan to n lọ lọwọ yii ni Gomina Abiọdun ti sọrọ idaniloju naa l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu karun-un, ọdun 2021, nigba to gba awọn aṣaaju ẹgbẹ APC nipinlẹ Ogun lalejo l’Abẹokuta nirọlẹ ọjọ naa.
Ẹ oo ranti pe lọjọ Iṣẹgun ni ijọba apapọ kede pe oun yoo ge owo-oṣu awọn oṣiṣẹ, awọn ẹka ileeṣẹ kọọkan to ti da wa tẹlẹ yoo si darapọ mọ awọn mi-in ki inawo ijọba le dinku.
Ṣugbọn bi wọn ṣe ṣinu tan lọjọ naa ni Abiọdun sọ fawọn olori APC to waa ki i pe kaka toun yoo fi ge owo-oṣu awọn oṣiṣẹ ku, ijọba oun yoo yaa maa tẹsiwaju ninu ọgbọn atinuda to fi n ran ọrọ aje ipinlẹ Ogun lọwọ ni.
Bakan naa ni Gomina Abiọdun fi awọn eeyan lọkan balẹ lori eto aabo nipinlẹ yii. O ni ijọba oun yoo gbe OPMESA jade pada laipẹ, iyẹn ikọ ologun ọtọọtọ ti wọn maa n para-pọ ṣiṣẹ aabo fawọn ipinlẹ. O ni wọn yoo ṣe ifilọlẹ ẹ pada yatọ si bo ṣe di nnkan igbagbe ninu ijọba ana nipinlẹ Ogun.
O tẹsiwaju pe laarin ọsẹ meji si mẹta ni ifilọlẹ OPMESA yii yoo waye, ti eyi yoo tun kun Amọtẹkun, ọlọpaa ati fijilante.
‘OPMESA ti lọ fun ọpọlọpọ ọdun nitori ijọba ana ko mu un lọkun-un-kundun, wọn si da a duro. Ṣugbọn emi tọpasẹ ẹ lọ, mo si ri ọga awọn ologun lati fọwọ si i, nitori mo sọ fun un pe emi o le fi eto aabo ṣere nipinlẹ temi, mi o mọ tawọn mi-in o’ Bẹẹ ni Gomina Abiọdun wi.
Bakan naa lo sọrọ lori ibo ijọba ibilẹ ti yoo waye lọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje, nipinlẹ Ogun. Abiọdun sọ pe ko sẹni ti yoo gbe ọmọ Ọba f’Ọṣun nibẹ, APC ko si ni i tori pe oun wa nijọba ko waa ṣeeru fawọn yooku.
Gomina ni ibo naa yoo ni akoyawọ pupọ, o ni bijọba ṣe gba awọn obinrin niyanju lati kopa nibẹ to, iyẹn ko tumọ si pe wọn yoo fi wọn kẹ awọn ọkunrin to ba fẹẹ dije.
Ninu iroyin mi-in, Gomina Dapọ Abiọdun ti ba Olori ijọ Ridiimu, Pasitọ Adejare Adeboye, kẹdun iku ọmọ rẹ, Oloogbe Dare Adeboye, to dagbere faye lojiji lẹni ọdun mejilelogoji.
Abiọdun ti lọọ ki Baba Adeboye nile, o si ṣapejuwe iku Dare toun naa jẹ pasitọ gẹgẹ bii0 ohun to ba ni lọkan jẹ, to si ṣeeyan ni kayeefi. O gbadura k’Ọlọrun fun baba lagbara lati gbe agbelebu yii, ko si duro ti ijọ Onirapada kaakiri agbaye.