Faith Adebọla
Awọn aṣofin ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP (Peoples Democratic Party) lati ileegbimọ aṣofin agba, iyẹn sẹnetọ atawọn aṣoju-ṣofin l’Abuja, ti ṣekilọ pe awọn o ni i fara mọ ọn bi Aarẹ Muhammadu ba tun ṣawawi kan lati ma ṣe buwọ lu abadofin eto idibo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ fi sọwọ si i, wọn lawọn reti pe ko buwọ lu u lai fakoko ṣofo mọ.
Bakan naa ni wọn fẹsun kan awọn gomina kan ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ati awọn oloṣelu ẹgbẹ naa, bo tilẹ jẹ pe wọn o darukọ ẹnikẹni, wọn laṣiiri ti tu sawọn lọwọ pe niṣe ni wọn n gbọna ẹyin sọ fun Buhari pe ko ma ṣe buwọlu abadofin naa, tori ki wọn le raaye ṣe magomago lasiko eto idibo gbogbogboo to n bọ lọdun 2023.
Alaga awọn aṣofin PDP ọhun, Sẹnetọ Enyinnaya Abaribe, to tun jẹ olori awọn aṣofin to kere ju lọ nileegbimọ agba, lo sọrọ yii lasiko toun atawọn aṣofin yooku ṣepade pẹlu igbimọ aṣeefọkantan ẹgbẹ PDP (Board of Trustee) lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, niluu Abuja.
O ni iṣẹ kekere kọ lawọn aṣofin ṣe lati gbe abadofin naa kalẹ, ko le bẹgi dina ọpọlọpọ ojooro ati magomago to maa n waye lasiko idibo nilẹ wa, bẹẹ lawọn si tun ṣatunṣe si awọn apa kan ofin ọhun, ti Buhari sọ pe oun o fara mọ tẹlẹ, awọn si ti yọ awọn ofin kan sọnu lati le mu ki Buhari buwọ lu u bo ṣe yẹ.
O ni ko tun yẹ ki Buhari tun ṣawawi kan mọ, paapaa nitori akoko to ṣẹku ti eto idibo 2023 yoo fi waye ko pọ mọ, bẹẹ ọpọ iṣẹ tuntun ni abadofin naa yoo gbe le ejika ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC (Independent Electoral Commission), ti wọn si gbọdọ ṣe e ṣaaju ọjọ idibo.
Bakan naa ni olori awọn aṣoju-ṣofin to kere ju lọ, Ọnarebu Ndudi Elumelu, sọ pe gbogbo bawọn gomina ẹgbẹ oṣelu APC kan ṣe n gbọna ẹyin sọ fun Buhari lati ma ṣe buwọlu abadofin naa lawọn n ri, o ni ẹru lo n ba wọn pe ko ni i saaye fun ojooro ati magomago ti ofin naa ba bẹrẹ iṣẹ, ṣugbọn awọn o ni i gba fun wọn.
O ni gbogbo awọn ọmọ orileede yii lo n reti eto idibo to muna doko, wọn si n reti pe ki Buhari buwọlu abadofin yii, lai fakoko ṣofo lori rẹ mọ.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu ki-in-ni, ọdun yii, ni ileegbimọ aṣofin taari abadofin ti wọn ṣatunṣe si ọhun sọdọ Aarẹ Buhari fun ibuwọlu rẹ, lati sọ ọ dofin.