Gbogbo awọn to lọwọ ninu didana sun oko mi lo maa geka abamọ jẹ – Ọbasanjọ

Faith Adebọla

Lasiko yii, inu Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ko dun rara, olori ilẹ wa tẹlẹ naa ko si fi pamọ, pẹlu ibinu lo fi sọrọ, o ni ko si ẹnikan ninu awọn to kopa ninu bi wọn ṣe dana sun oko oun to wa niluu Howe, lagbegbe Aliade, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Gwer, nipinlẹ Benue, to maa ribi sa lọ, o loun maa ri i daju pe gbogbo wọn jiya to tọ si wọn fun iwa buruku ti wọn hu ọhun.

Ọbasanjọ sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi lede niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, nipasẹ Oluranlọwọ rẹ feto iroyin, Ọgbẹni Kẹhinde Akinyẹmi, o lawọn agbofinro atawọn ọtẹlẹmuyẹ ti n ṣiṣẹ lati wa gbogbo awọn to huwa ibajẹ ọhun lawaari.

Ọbasanjọ tun dupẹ gidigidi lọwọ gbogbo awọn to tẹ ẹ laago atawọn to fi mẹseeji ṣọwọ si i lori iṣẹlẹ ọhun. O ni ko si igbesẹ idajọ idodo kan toun ko ni i gbe lati ri i daju pe awọn to huwa aidaa naa jiya iṣẹ ọwọ wọn.

O tun dupẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Benue ati ijọba ibilẹ ti oko naa wa, fun bi wọn ṣe ṣeranwọ lati pa ina naa, ti wọn si tete bẹrẹ si i fimu finlẹ lati mọ awọn to wa nidii ijamba ọhun.

Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom, kede ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lori iṣẹlẹ naa pe iwa ọdaran paraku lawọn to lọọ fina soko ọhun hu, ijọba oun si maa wa gbogbo wọn lawaari, wọn maa fimu kata ofin gidi ni.

Ṣe nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu ki-in-ni, to kọja yii, lawọn afurasi janduku kan lọọ binu sọ ina si oko eeso Orchard Farm, ti i ṣe ti Oloye Ọbasanjọ, nipinlẹ Benue.

Ina naa ṣọṣẹ gidi lori sare ilẹ ẹgbẹrun meji aabọ hẹkita ti oko naa wa, ọpọlọpọ ọsan, ibẹpẹ, mangoro, ọgẹdẹ atawọn eso pẹlu nnkan ọgbin mi-in lo ṣegbe.

Ko ti i sẹni to mọ pato nnkan to bi awọn eeyan naa ninu ti wọn fi gbe igbesẹ buruku ọhun, ṣugbọn iwadii ti n tẹsiwaju.

Leave a Reply