Faith Adebọla
“Ileeṣẹ NYSC to n bojuto awọn agunbanirọ ko ni i laju silẹ ki talubọ ko wọ ọ. A maa rọ mọ gbogbo ilana ati alakalẹ ijọba lori arun Koronafairọọsi timọtimọ ni. Bẹrẹ lati oṣukin-in-ni, ọdun to n bọ yii, a o ni i jẹ ki akẹkọọ-gboye eyikeyii ti ko ti i gba abẹrẹ ajẹsara Korona kopa ninu iṣẹ isinlu tawọn agunbanirọ n ṣe, tori oju lalakan fi n ṣọri.”
Ọga agba patapata fun ileeṣẹ National Youth Service Corps (NYSC), Ọgagun agba Shuaibu Ibrahim, lo kede ọrọ ikilọ yii ninu ọrọ akanṣe kan to ba gbogbo awọn agunbanirọ 2021, isọri kẹta (Batch C), sọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtala, oṣu Disẹmba yii.
Ninu ọrọ ọhun, eyi ti wọn ta atagba rẹ kaakiri gbogbo ibudo idanilẹkọọ awọn agunbanirọ to wa kaakiri awọn ipinlẹ mẹrindinlogoji ati olu-ilu ilẹ wa, Abuja, Shuaibu sọ pe bijọba ṣe ṣawari ẹya arun Korona tuntun ti wọn pe ni Omicron gbọdọ mu ki gbogbo awọn ọdọ sunra ki, ki wọn si wa lojufo.
Latari eyi, o ni dandan ni kawọn akẹkọọ-gboye to fẹẹ ṣiṣẹ sinlu fi ẹri to fidi mulẹ han lẹnu geeti pe awọn ti gba abẹrẹ ajẹsara Korona, ilera awọn si ta sansan ki wọn too gba wọn wọle sibudo agunbanirọ, bẹrẹ lati ọjọ ki-in-ni, oṣu ki-in-ni, ọdun 2022.
Bakan naa lo sọ pe eto ti n lọ lọwọ lati maa pese owo iranwọ ati owo idokoowo fawọn agunbanirọ to ba fẹẹ bẹrẹ okoowo tabi ẹkọṣẹ lẹyin iṣẹ aṣẹsinlu wọn, tori naa, o rọ awọn agunbanirọ lati fọwọ pataki mu ẹkọṣẹ ọwọ ati awọn ọna okoowo pẹẹpẹẹpẹ mi-in ti wọn n kọ wọn lasiko idanilẹkọọ wọn, o lawọn ọdọ to nikan-an-ṣe lawọn fẹẹ ran lọwọ.
Shuaibu tun gba awọn ọdọ naa nimọran lati yẹra fun irinajo eyikeyii to maa mu ki wọn wa lode lẹyin aago mẹfa aṣalẹ.
“Ẹ yee wọ mọto ifa, ẹ ma wọkọ ọfẹ, ẹ ri i pe ẹ ti pada wọle yin taago mẹfa irọlẹ ba ti lu, ẹ ma lọ sibikan lai dagbere, ẹ ma duro sibi to lewu lẹyin nikan. Ẹ ṣọ awọn tẹ ẹ maa ba ṣọrẹ tuntun, ẹ si kiyesara lawọn otẹẹli tẹ ẹ ba fẹẹ lo si,” bẹẹ l’Ọga agba naa sọ.